Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Orílẹ̀-èdè Jámánì

Orílẹ̀-èdè Botswana

Orílẹ̀-èdè Nicaragua

Orílẹ̀-èdè Ítálì

Kí nìdí tínú àwọn èèyàn yìí fi ń dùn? Wọ́n wà ní ọ̀kan lára àwọn àpéjọ wa ni. Bíi ti àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́, tí Ọlọ́run fún ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa lọ sí àpéjọ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, a máa ń fojú sọ́nà fún lílọ sí àwọn àpéjọ ńlá. (Diutarónómì 16:16) Lọ́dọọdún, a ní àpéjọ méjì: Àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ kan, àmọ́ méjì irú ẹ̀ la máa ṣe ní ọdún iṣẹ́ ìsìn, àti àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta. Báwo ni àwọn àpéjọ yìí ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

Wọ́n ń mú kí ẹgbẹ́ ará wa wà níṣọ̀kan. Bí inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń yin Jèhófà ní “inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn,” bẹ́ẹ̀ náà ni inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá ń jọ́sìn rẹ̀ nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. (Sáàmù 26:12; 111:1) Àwọn àpéjọ yìí máa ń fún wa láǹfààní láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti àwọn ìjọ míì tàbí àwọn orílẹ̀-èdè míì pàápàá. Ní ọ̀sán a máa ń jẹun ní gbọ̀ngàn àpéjọ wa, èyí sì túbọ̀ ń jẹ́ ká gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ láwọn àpéjọ náà. (Ìṣe 2:42) Láwọn àpéjọ yìí, a máa ń fojú ara wa rí i pé ìfẹ́ ló so “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” wa pọ̀ kárí ayé.—1 Pétérù 2:17.

Wọ́n ń mú ká tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jàǹfààní bí wọ́n ti ń “lóye ọ̀rọ̀” inú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń ṣàlàyé fún wọn. (Nehemáyà 8:8, 12) Àwa náà mọyì ìtọ́ni Bíbélì tí á máa ń gbà láwọn àpéjọ wa. Orí Ìwé Mímọ́ la gbé àwọn ẹ̀kọ́ náà kà. Nípasẹ̀ àsọyé alárinrin, àpínsọ àsọyé àtàwọn àṣefihàn ìrírí tí ẹnì kan ní, a máa ń kọ́ bí a ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbèésí ayé wa. A máa ń rí ìṣírí gbà nígbà tá a bá gbọ́ bí àwọn ará wa ṣe ń fara da ìṣòro tó ń dé bá àwọn Kristẹni tòótọ́ lákòókò tó le koko yìí. Ní àwọn àpéjọ àgbègbè wa, àwòkẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú àwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe kedere, wọ́n sì ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ gidi. Ní gbogbo àpéjọ, wọ́n máa ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn tó fẹ́ fi hàn pé àwọn ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

  • Kí nìdí tí àwọn àpéjọ wa fi máa ń fún wa láyọ̀?

  • Báwo lo ṣe lè jàǹfààní nígbà tó o bá lọ sí àpéjọ kan?