Orílẹ̀-èdè New Zealand

Japan

Orílẹ̀-èdè Uganda

Orílẹ̀-èdè Lithuania

Nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀, ohun tí wọ́n máa ń ṣe ní àwọn ìpàdé ìjọ ni pé wọ́n máa ń kọrin, wọ́n máa ń gbàdúrà, wọ́n ń ka Ìwé Mímọ́, wọ́n sì ń jíròrò wọn, wọn kò ní àwọn ààtò ìsìn kankan. (1 Kọ́ríńtì 14:26) Ohun kan náà là ń ṣe láwọn ìpàdé wa.

Ìtọ́ni tó gbéṣẹ́ látinú Bíbélì. Ní ìparí ọ̀sẹ̀, ìjọ kọ̀ọ̀kàn máa ń péjọ láti gbọ́ Àsọyé Bíbélì ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú tó ń sọ nípa bí Ìwé Mímọ́ ṣe lè mú kí ìgbésí ayé wa dára, tí ó sì ń jẹ́ kí á mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yìí. Wọ́n máa ń rọ gbogbo wa láti gbé Bíbélì wa ká sì máa fojú bá ibi tí wọ́n ń kà lọ. Lẹ́yìn àsọyé náà, a máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́” oníwákàtí kan, a sì máa ń rọ gbogbo ara ìjọ láti kópa nínú ìjíròrò àpilẹ̀kọ kan nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìjíròrò yìí máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wa. Àpilẹ̀kọ kan náà la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìjọ wa tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [110,000] lọ kárí ayé.

Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀nà tí à ń gbà kọ́ni dára sí i. A tún ń péjọ ní ìrọ̀lẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀ fún ìpàdé alápá mẹ́ta táa ń pè ní Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kritẹni. Ìtòlẹ́sẹ́ẹsẹ tó wà nínú Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kritẹni–Ìwé Ìpàdé la gbé ìpàdé yìí kà. Apá àkọ́kọ́ lára ìpàdé náà ni Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye apá Bíbélì táwọn ará múra sílẹ̀ ṣáájú. Lẹ́yìn ìyẹn ni Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù níbi tí a ti máa ṣàṣefihàn bí a ṣe lè bá àwọn èèyàn jíròrò láti inú Bíbélì. Agbani-nímọ̀ràn kan wà tó máa ń kíyè sí ọ̀rọ̀ wa kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìwé kíkà àti ọ̀rọ̀ sísọ wa dára sí i. (1 Tímótì 4:​13) Apá tó gbẹ̀yì nínú ìpàdé náà ni Máa Hùwà Tó Yẹ Kritẹni níbi táa ti máa ń jíròrò bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lójoojúmọ́, nígbèésí ayé wa. Ó tún máa ń ní ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn tó máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye Bíbélì.

Tó o bá wá sí àwọn ìpàdé wa, kò sí àní-àní pé inú rẹ yóò dùn láti rí ẹ̀kọ́ àtàtà kọ́ látinú Bíbélì.—Aísáyà 54:13.

  • Kí lo máa kọ́ láwọn ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

  • Èwo nínú ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ló wù ẹ́ láti lọ?