Ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní

Wọ́n ń ka lẹ́tà tí ìgbìmọ̀ olùdarí kọ

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwùjọ kékeré kan, ìyẹn “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn [alàgbà] ní Jerúsálẹ́mù,” ló jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí tó ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì fún àǹfààní gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. (Ìṣe 15:2) Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa ń jíròrò àti ẹ̀mí Ọlọ́run tí wọ́n ń jẹ́ kó darí wọn, ló ń mú kí wọ́n máa ṣe ìpinnu ní ìfohùnṣọ̀kan. (Ìṣe 15:25) Àpẹẹrẹ yẹn là ń tẹ̀ lé lóde òní.

Ọlọ́run ń lò ìgbìmọ̀ náà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an, àwọn arákùnrin náà sì ní ìrírí tó pọ̀ nípa bá a ṣe ń bójú tó àwọn ọ̀ràn iṣẹ́ àti ìjọsìn wa. Wọ́n máa ń pàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti jíròrò ohun tí ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé nílò. Bíi ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, à ń rí àwọn ìtọ́ni tá a gbé ka Bíbélì gbà nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí nípasẹ̀ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn míì. Èyí ń jẹ́ kí èrò àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣọ̀kan, kí wọ́n sì máa ṣe ohun kan náà. (Ìṣe 16:4, 5) Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí, wọ́n ń rọ àwọn ará láti fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń bójú tó yíyan àwọn arákùnrin sípò.

Ìgbìmọ̀ náà ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun. Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń gbára lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti ti Jésù tí í ṣe Orí ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:23) Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí kì í wo ara wọn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn àti gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [Jésù] lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.” (Ìṣípayá 14:4) Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọrírì àdúrà tí à ń gbà nítorí wọn.

  • Àwọn wo ló jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

  • Báwo ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?