Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 21

Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?

Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?

Ẹ̀ka Àwòrán Yíyà, Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Orílẹ̀-èdè Jámánì

Orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà

Orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà

Bẹ́tẹ́lì jẹ́ orúkọ kan lédè Hébérù tí ó túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.” (Jẹ́nẹ́sísì 28:17, 19) Orúkọ tó bá a mu yìí la fi ń pe àwọn ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ kárí ayé, tí à ń lò láti fi darí iṣẹ́ ìwàásù, tí a sì fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Orílé-iṣẹ́ wa wà ní ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibẹ̀ sì ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń bójú tó iṣẹ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ìdílé Bẹ́tẹ́lì là ń pe àpapọ̀ àwọn tó ń sìn ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bí ìdílé kan, wọ́n ń gbé pa pọ̀, wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, wọ́n ń jẹun pa pọ̀, wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan.—Sáàmù 133:1.

Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi àrà ọ̀tọ̀ kan, tí àwọn èèyàn ti máa ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú. Ní gbogbo ilé Bẹ́tẹ́lì, wàá rí àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ńṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn, tí wọ́n sì ń lo gbogbo àkókò wọn láti bójú tó àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 6:33) Wọn kì í gba owó oṣù, àmọ́ wọ́n fún wọn ní yàrá, oúnjẹ àti owó ìtìlẹ́yìn tí wọ́n lè lò fún àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Gbogbo ẹni tó wà ní Bẹ́tẹ́lì la yan iṣẹ́ fún, yálà ní ọ́fíìsì, ní ilé ìdáná tàbí ní yàrá ìjẹun. Àwọn kan ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtẹ̀wé tàbí ibi ìdìwépọ̀ tàbí kí wọ́n máa tọ́jú ilé, kí wọ́n máa fọṣọ, kí wọ́n máa tún nǹkan ṣe, tàbí kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ míì.

Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí tí a fi kọ́ àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì ni láti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Àpẹẹrẹ kan ni ìwé yìí. A kọ ọ́ lábẹ́ àbójútó Ìgbìmọ̀ Olùdarí, a lo kọ̀ǹpútà láti fi í ránṣẹ́ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn atúmọ̀ èdè, a fi ẹ̀rọ ayára-bí-àṣá tẹ̀ ẹ́ ní àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì tí a ti ń tẹ̀wé, a sì kó o lọ sí àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [110,000]. Gbogbo iṣẹ́ yẹn ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.—Máàkù 13:10.

  • Àwọn wo ló ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì, báwo la sì ṣe ń tọ́jú wọn?

  • Iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú wo ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì kọ̀ọ̀kan ń tì lẹ́yìn?