Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 27

Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Tó Wà Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Tó Wà Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Orílẹ̀-èdè Israel

Orílẹ̀-èdè Czech Republic

Orílẹ̀-èdè Benin

Àwọn Erékùṣù Cayman Islands

Ǹjẹ́ o fẹ́ láti ṣe àwọn ìwádìí kan láti mú kí ìmọ̀ rẹ nínú Bíbélì pọ̀ sí i? Ṣé o fẹ́ láti mọ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí èèyàn kan, nípa ibi kan tàbí ohun kan nínú Bíbélì? Tàbí ò ń ṣe kàyéfì bóyá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ohun kan tó ò ń ṣàníyàn lé lórí? Lọ ṣèwádìí ní ibi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Àwọn ìwé téèyàn lè fi ṣèwádìí wà níbẹ̀. O lè máà ní gbogbo ìwé tí a gbé karí Bíbélì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní èdè rẹ. Àmọ́, ibi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba ní púpọ̀ lára àwọn ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Àwọn ìwé tó tún lè wà níbẹ̀ ni oríṣiríṣi ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì, ìwé atúmọ̀ èdè àtàwọn ìwé míì tá a lè ṣèwádìí nínú wọn. Kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé, o lè lo àwọn ìwé tó wà níbi ìkówèésí. Bí kọ̀ǹpútà bá wà níbẹ̀, ó lè ní ètò Watchtower Library [ìyẹn àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM]. Ètò ìṣiṣẹ́ Kọ̀ǹpútà yìí ní àkójọ ọ̀pọ̀ ìwé wa, ó sì rọrùn láti lò ó fún ṣíṣe ìwádìí nípa kókó ẹ̀kọ́ kan, ọ̀rọ̀ kan tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan.

Ó wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kritẹni. O lè jàǹfààní tó o bá lo ibi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba láti múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀. Alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ló ń bójú tó ibi ìkówèésí náà. Òun ló máa ń rí sí i pé àwọn ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde wà níbẹ̀ àti pé kí gbogbo ìwé ibẹ̀ wà létòlétò. Alábòójútó náà tàbí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè fi bó o ṣe máa rí ìsọfúnni tó o nílò hàn ẹ́. Àmọ́, má ṣe mú ìwé èyíkéyìí kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bákan náà, a ní láti tọ́jú àwọn ìwé náà dáádáá kí á má sì kọ nǹkan kan sínú wọn.

Bíbélì ṣàlàyé pé tá a bá fẹ́ “rí ìmọ̀ Ọlọ́run,” a gbọ́dọ̀ máa wá a kiri “bí àwọn ìṣúra fífarasin.” (Òwe 2:1-5) Ibi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í wá a.

  • Àwọn ohun wo tá a lè fi ṣe ìwádìí ló wà ní ibi ìkówèésí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

  • Ta ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè lo ibi ìkówèésí lọ́nà tó máa ṣe ọ́ láǹfààní?