Orílẹ̀-èdè Madagásíkà

Orílẹ̀-èdè Norway

Orílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì

Orílẹ̀-èdè Ítálì

A máa ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, àní bó bá tiẹ̀ gba pé ká rìn gba àárín igbó kìjikìji tàbí ká fara da ojú ọjọ́ tí kò bára dé. Láìka àwọn ìṣòro ìgbésí ayé sí àti àárẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń sapá láti péjọ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

Ó ń gbé wa ró. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tá a máa ń bá kẹ́gbẹ́ nínú ìjọ, ó sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì.’ (Hébérù 10:24) Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí “ronú dáadáa nípa,” ìyẹn ni láti mọ ara wa. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì náà ń rọ̀ wá láti máa ronú nípa àwọn ẹlòmíì. Tá a bá mọ àwọn ìdílé míì tá a jọ jẹ́ Kristẹni, a máa rí i pé àwọn kan lára wọn ti borí àwọn ìṣòro tó jọ tiwa, wọ́n sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí tiwa.

Ó ń jẹ́ ká ní ọ̀rẹ́ àtàtà. Ní àwọn ìpàdé wa, a máa ń péjọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, wọn kì í ṣe ojúlùmọ̀ lásán, ọ̀rẹ́ àtàtà ni wọ́n jẹ́. Láwọn ìgbà míì, a jọ máa ń ṣe eré ìnàjú tó gbámúṣé. Àǹfààní wo ni irú ìbákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe wá? Ó ń mú ká túbọ̀ mọyì ara wa, ó sì ń jẹ́ kí ìfẹ́ àárín wa lágbára sí i. Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ wa yìí bá wá dojú kọ ìṣòro, a máa ń múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nítorí pé ọ̀rẹ́ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún wa. (Òwe 17:17) Tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ìjọ, à ń fi hàn pé a “ní aájò kan náà fún ara [wa].”—1 Kọ́ríńtì 12:25, 26.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o mú àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́rẹ̀ẹ́. Wàá rí irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti dara pọ̀ mọ́ wa.

  • Kí nìdí tí ìbákẹ́gbẹ́ ní àwọn ìpàdé wa fi máa ń ṣe wá láǹfààní?

  • Ìgbà wo lo máa bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé ìjọ wa?