Orílẹ̀-èdè Bolivia

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ àti bó ṣe rí nísinsìnyí

Orílẹ̀-èdè Tahiti

Bí orúkọ náà Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe fi hàn, ohun ta a máa ń jíròrò níbẹ̀ ni ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú Bíbélì nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀kọ́ Jésù dá lé.—Lúùkù 8:1.

Wọ́n jẹ́ ibi tá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ ní àdúgbò wa. Látinú Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti máa ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń tóbi ju ara wọn lọ, wọ́n sì yàtọ̀ síra, àmọ́ wọn kì í tóbi jù, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń ní ju ìjọ kan lọ. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba (tá a bá pín in sí ọgbọọgba, márùn-ún là ń kọ́ lójúmọ́) kí á bàa lè rí àyè fún àwọn ìjọ wa tó ń pọ̀ sí i. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe?—Mátíù 19:26.

Ọrẹ tí gbogbo wa ń mú wá la fi ń kọ́ wọn. A máa ń fi ọrẹ yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kí wọ́n lè fi owó ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ tó fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí tí wọ́n fẹ́ tún un ṣe.

Àwọn èèyàn tí ipò ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ síra tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn láìgbowó ló máa ń kọ́ wọn. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a ti ṣètò Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwùjọ àwọn ìránṣẹ́ ìkọ́lé àti àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń lọ láti ìjọ kan sí òmíràn, kódà wọ́n ń lọ sí àwọn ibi tó jìnnà ní orílẹ̀-èdè kan náà, kí wọ́n lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ní àwọn ilẹ̀ míì, àwọn arákùnrin tí wọ́n kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ máa ń ṣàbójútó kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ṣíṣe àtúnṣe sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lágbègbè kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa ń yọ̀ǹda ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ní gbogbo ibi tá a ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ará ìjọ tó máa lo gbọ̀ngàn náà ló máa ń pọ̀ jù lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà. Ẹ̀mí Jèhófà àti iṣẹ́ àṣekára àwọn èèyàn rẹ̀ látọkànwá ló ń mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe.—Sáàmù 127:1; Kólósè 3:23.

  • Kí nìdí tá a fi ń pe àwọn ilé ìjọsìn wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba?

  • Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba káàkiri ayé?