Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 19

Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?

Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?

Gbogbo wa pátá là ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí

Nígbà tí ikú Jésù ti sún mọ́lé gan-an, ó bá mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́, ìyẹn Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Áńdérù. Bó ṣe ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àmì wíwà níhìn-ín rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn, ó béèrè ìbéèrè pàtàkì kan pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?” (Mátíù 24:3, 45; Máàkù 13:3, 4) Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun tí òun jẹ́ “ọ̀gá” wọn, máa yan àwọn táá máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí déédéé fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní àkókò òpin. Àwọn wo ló máa para pọ̀ jẹ́ ẹrú náà?

Ó jẹ́ àwùjọ kékeré àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. “Ẹgbẹ́ ẹrú” náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó máa ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. A gbára lé ẹrú olóòótọ́ yìí láti máa fún wa ní “ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ” wa “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Lúùkù 12:42.

Ó ń bójú tó agbo ilé Ọlọ́run. (1 Tímótì 3:15) Jésù gbé iṣẹ́ ńlá fún ẹrú náà láti máa bójú tó iṣẹ́ tó jẹ́ ti apá orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà, ìyẹn bíbójútó ohun ìní rẹ̀, dídarí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ wa nípasẹ̀ ìjọ wa. Nítorí náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè ohun tá a nílò fún wa ní àkókò tó yẹ, ìyẹn sì jẹ́ nípa pínpín oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn ìwé tá à ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù wa àti nípasẹ̀ àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí à ń gbọ́ ní àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.

Ẹrú náà jẹ́ olóòótọ́ sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni àti iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Bíbélì pa láṣẹ, ó sì jẹ́ olóye nítorí pé ó ń fi ọgbọ́n bójú tó àwọn ohun ìní Kristi láyé. (Ìṣe 10:42) Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ẹrú náà, ó ń jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì ń mú kí wọ́n ní oúnjẹ tẹ̀mí tó pọ̀ gan-an.—Aísáyà 60:22; 65:13.

  • Ta ni Jésù yàn láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

  • Ọ̀nà wo ni ẹrú náà gbà jẹ́ olóòótọ́ àti olóye?