Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 12

Báwo La Ṣe Ṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run Tí À Ń Ṣe?

Báwo La Ṣe Ṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run Tí À Ń Ṣe?

Orílẹ̀-èdè Sípéènì

Orílẹ̀-èdè Belarus

Orílẹ̀-èdè Hong Kong

Orílẹ̀-èdè Peru

Nígbà tí ikú Jésù ti sún mọ́lé gan-an, ó kéde pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Àmọ́, báwo la ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó máa kárí ayé yìí? Bí a ṣe máa ṣe é ni pé, a ó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó wà láyé.—Lúùkù 8:1.

À ń sapá láti lọ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní ilé wọn. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa wàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé. (Mátíù 10:11-13; Ìṣe 5:42; 20:20) Àwọn ajíhìnrere ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní yẹn ní ìpínlẹ̀ pàtó tí wọ́n ti ń wàásù. (Mátíù 10:5, 6; 2 Kọ́ríńtì 10:13) Bákan náà lónìí, a ṣètò iṣẹ́ ìwàásù wa dáadáa, a sì fún ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ibi tó ti máa wàásù. Èyí jẹ́ ká lè máa tẹ̀ lé àṣẹ́ tí Jésù fún wa láti “wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.”—Ìṣe 10:42.

À ń sapá láti máa wàásù fún àwọn èèyàn níbi yòówù tá a ti lè rí wọ́n. Jésù tún fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú wíwàásù níbi táwọn èèyàn wà, irú bí etíkun tàbí nídìí kànga àdúgbò. (Máàkù 4:1; Jòhánù 4:5-15) Àwa náà máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì níbi yòówù tá a ti lè ṣe é, ìyẹn ní ojú pópó, níbi iṣẹ́, nínú ọgbà ìgbafẹ́ tàbí lórí fóònù. A tún máa ń wàásù fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ iléèwé wa àtàwọn ẹbí wa, nígbà tí àǹfààní bá wà láti ṣe é. Gbogbo ìsapá tí à ń ṣe yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé láti gbọ́ “ìhìn rere ìgbàlà.”—Sáàmù 96:2.

Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ẹni tó o máa fẹ́ bá sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí ìhìn rere náà máa ṣe fún wọn lọ́jọ́ iwájú? Má ṣàìsọ ìrètí náà fún àwọn èèyàn. Sọ ọ́ nígbàkigbà tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ!

  • “Ìhìn rere” wo ni a gbọ́dọ̀ polongo?

  • Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

Mọ Púpọ̀ Sí I