Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 10

Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?

Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?

Orílẹ̀-èdè South Kòríà

Orílẹ̀-èdè Brazil

Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà

Orílẹ̀-èdè Guinea

Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti fẹ́ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní àkókò tí wọ́n á jọ máa lò pa pọ̀, kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ òun kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. (Diutarónómì 6:6, 7) Ìdí nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ya àkókò kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìdílé láti jọ́sìn pa pọ̀, wọ́n á jókòó pẹ̀sẹ̀, wọ́n á sì jíròrò àwọn nǹkan tó máa mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Kódà tó bá jẹ́ pé ò ń dá gbé ni, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ kókó kan tó o fẹ́ nínú Bíbélì.

Ó jẹ́ àkókò láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) A máa túbọ̀ mọ Jèhófà nígbà tí a bá mọ púpọ̀ sí i nípa ànímọ́ rẹ̀ àti ìhùwàsí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀nà kan tó rọrùn láti gbà bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn ìdílé rẹ ni pé kí ẹ ka Bíbélì sókè. Ẹ lè máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kritẹni. Ẹ lè yan apá kan nínú Bíbélì náà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé láti kà, kí gbogbo yín sì jíròrò ohun tí ẹ kọ́ níbẹ̀.

Ó jẹ́ àkókò láti mú kí ìdílé túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Àwọn tọkọtaya, àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn máa ń túbọ̀ wà níṣọ̀kan tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ó yẹ kí ó jẹ́ àkókò ayọ̀ àti àlàáfíà, kí ó sì tún jẹ́ ohun tí wọ́n á máa wo ọ̀nà fún lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn òbí lè yan ohun tí wọ́n máa jíròrò gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí àwọn ọmọ wọn bá ṣe rí, wọ́n lè yan àkòrí kan láti inú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tàbí láti orí ìkànnì jw.org/yo. Ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tí àwọn ọmọ dojú kọ́ nílé ìwé àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ̀. Ẹ ò ṣe wò lára àwọn ètò tó wà lórí Tẹlifíṣọ̀n JW (tv.jw.org) kẹ́ẹ sì jọ jíròrò nípa rẹ̀. Ẹ lè gbádùn fífi orin tí a máa kọ ní ìpàdé dánra wò. Ẹ sì lè jẹ ìpápánu lẹ́yìn ìjọsìn ìdílé yín.

Àkókò pàtàkì tí ẹ̀ ń lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ yìí máa ran gbogbo yín lọ́wọ́ láti rí ìdùnnú nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò sì mú kí ìsapá yín yọrí sí rere.—Sáàmù 1:1-3.

  • Kí nìdí tá a fi ya àkókò sọ́tọ̀ fún ìjọsìn ìdílé?

  • Báwo ni àwọn òbí ṣe lè jẹ́ kí gbogbo ìdílé gbádùn ìjọsìn ìdílé?