Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 22

Kí Là Ń Ṣe Ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?

Kí Là Ń Ṣe Ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?

Orílẹ̀-èdè Solomon Islands

Orílẹ̀-èdè Kánádà

Orílẹ̀-èdè South Africa

Ẹ̀ka iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwùjọ atúmọ̀ èdè, kí wọ́n máa tẹ ìwé ìròyìn, kí wọ́n máa di ìwé pọ̀, kí wọ́n kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí ibi ìkówèésí, kí wọ́n máa gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ tàbí kí wọ́n máa bójú tó àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ àgbègbè tó wà lábẹ́ àbójútó wọn.

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ló ń bójú tó iṣẹ́ ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan. Ìgbìmọ̀ Olùdarí fa àbójútó ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan lé Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lọ́wọ́, ìyẹn àwọn alàgbà mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n. Ìgbìmọ̀ yìí máa ń jẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọ ìtẹ̀síwájú tó ń bá iṣẹ́ wa ní ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó wà lábẹ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà àti ìṣòro tó bá yọjú. Irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí Ìgbìmọ̀ Olùdarí mọ ohun tó yẹ kí wọn gbé jáde nínú àwọn ìwé àti ohun tó yẹ ká jíròrò ní àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ lọ́jọ́ iwájú. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún máa ń rán àwọn aṣojú wọn láti máa lọ bẹ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wò déédéé kí wọ́n sì tọ́ àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ́nà nípa bí wọ́n ṣe máa bójú tó iṣẹ́ wọn. (Òwe 11:14) Lára àkànṣe ètò tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ìbẹ̀wò náà ni àsọyé tí aṣojú orílé-iṣẹ́ máa ń sọ láti fún àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì náà níṣìírí.

Wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ìjọ tó wà lágbègbè wọn. A fún àwọn arákùnrin kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa láṣẹ láti fọwọ́ sí dídá ìjọ tuntun sílẹ̀. Àwọn arákùnrin kan ló sì ń bójú tó iṣẹ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà, míṣọ́nnárì àti alábòójútó àyíká tó ń sìn ní ìpínlẹ̀ ẹ̀ka náà. Wọ́n máa ń ṣètò àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè, wọ́n ń dárí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, wọ́n ń rí sí i pé wọ́n fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn ìjọ nílò ránṣẹ́ sí wọn. Gbogbo iṣẹ́ tí à ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù máa lọ déédéé.—1 Kọ́ríńtì 14:33, 40.

  • Báwo ni àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ṣe ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́?

  • Àwọn iṣẹ́ wo là ń ṣe láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa?