Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 1

Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Orílẹ̀-èdè Denmark

Orílẹ̀-èdè Taiwan

Orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà

Orílẹ̀-èdè Íńdíà

Mélòó lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo mọ̀? Àwọn kan lára wa lè máa gbé ní àdúgbò rẹ, ìwọ àtàwọn kan sì lè jọ máa ṣiṣẹ́ tàbí kí ẹ jọ máa lọ sí ilé ìwé. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ti bá ẹ sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì rí. Irú èèyàn wo ni wa, kí sì nìdí tá a fi máa ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn?

Èèyàn bíi tiyín ni wá. Látinú onírúurú ìran, ẹ̀yà àti àwùjọ èèyàn la ti wá. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn kan lára wa ń ṣe, àwọn kan kò sì gbà pé Ọlọ́run wà. Àmọ́, kí a tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo wa la ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Ìṣe 17:11) A gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ tá a kọ́, a sì pinnu fúnra wa pé Jèhófà Ọlọ́run ni a máa sìn.

A ń jàǹfààní látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bíi ti gbogbo èèyàn, àwa náà ní àwọn ìṣòro àti ìkùdíẹ̀-káàtó tiwa. Àmọ́ bí a ṣe ń sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lójoojúmọ́, a ti rí i pé ìgbésí ayé wa ti dára sí i. (Sáàmù 128:1, 2) Ọ̀kan lára ìdí tó mú ká máa sọ àwọn ohun rere tá a ti kọ́ látinú Bíbélì fún àwọn èèyàn nìyẹn.

Àwọn ìlànà Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé ní ìgbésí ayé wa. Àwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ń ṣe wá láǹfààní, ó ń mú kí a bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn, ó tún ń mú kí a ní àwọn ìwà míì irú bí inú rere àti àìlábòsí. Àwọn ìlànà yìí máa ń mú kí ìlera àwọn èèyàn túbọ̀ dára sí i, ó ń mú kí wọ́n wúlò láwùjọ, ó ń mú kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan kí wọ́n sì ní ìwà rere. Nítorí a gbà pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” ìdí nìyẹn tí a fi jẹ́ ìdílé kan tó kárí ayé, tí ìgbàgbọ́ wa sì ṣọ̀kan, ìyẹn sì ló fà á tí a kì í gbé ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ, tí a kì í sì lọ́wọ́ sí ìṣèlú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́nì kọ̀ọ̀kan a kò yàtọ̀ sí àwọn èèyàn yòókù, àmọ́ lápapọ̀ èèyàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni wá.—Ìṣe 4:13; 10:34, 35.

  • Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi yàtọ̀ sí àwọn èèyàn yòókù?

  • Àwọn ìlànà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ láti inú Bíbélì?