Orílẹ̀-èdè Finland

Wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́

Wọ́n ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn

Wọ́n ń wàásù

A kò ní àwọn àlùfáà tó ń gba owó nínú ètò wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a yan àwọn alábòójútó tó kúnjú ìwọ̀n sípò “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run” gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe nígbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 20:28) Àwọn alàgbà yìí jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, tí wọ́n ń mú ipò iwájú nínú ìjọ, tí wọ́n sì ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, “kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.” (1 Pétérù 5:1-3) Iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe nítorí wa?

Wọ́n ń bójú tó wa, wọ́n sì ń dáàbò bò wá. Àwọn alàgbà ń tọ́ wa sọ́nà, wọ́n sì ń mú kí ìjọ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Bí àwọn alàgbà ti mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbé iṣẹ́ pàtàkì yìí lé àwọn lọ́wọ́, wọn kì í jọ̀gá lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú kí àlàáfíà àti ayọ̀ wa pọ̀ sí i. (2 Kọ́ríńtì 1:24) Bí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe ń tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alàgbà ṣe ń sapá láti mọ gbogbo ará ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Òwe 27:23.

Wọ́n ń kọ́ wa bí a ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn alàgbà máa ń darí àwọn ìpàdé ìjọ láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. (Ìṣe 15:32) Àwọn ọkùnrin olùfọkànsìn yìí tún máa ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa, wọ́n sì ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú gbogbo apá iṣẹ́ ìwàásù.

Wọ́n ń fún wa ní ìṣírí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nítorí kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn alàgbà máa ń bẹ̀ wá wò ní ilé wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti fi Ìwé Mímọ́ tù wá nínú, kí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́.—Jákọ́bù 5:14, 15.

Yàtọ̀ sí iṣẹ́ wọn nínú ìjọ, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn alàgbà tún ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ojúṣe nínú ìdílé tó ń gba àkókò àti àfiyèsí wọn. Ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára yìí.—1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.

  • Kí ni iṣẹ́ àwọn alàgbà ìjọ?

  • Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà ń gbà fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?