Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 17

Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?

Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?

Orílẹ̀-èdè Malawi

Àwùjọ àwọn tó fẹ́ lọ wàásù

Wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

Ìpàdé àwọn alàgbà

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, wọ́n sì ń bẹ àwọn ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà yẹn wò. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ àwọn ará tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run máa ń jẹ wọ́n lógún gan-an ni. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun fẹ́ láti “padà lọ bẹ àwọn ará wò” kí òun lè rí bí wọ́n ti ń ṣe sí. Ó múra tán láti rin ìrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà kó bàa lè lọ fún wọn lókun. (Ìṣe 15:36) Ohun kan náà tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò wa máa ń ṣe lónìí nìyẹn.

Wọ́n ń bẹ̀ wá wò láti fún wa níṣìírí. Alábòójútó àyíká máa ń bẹ nǹkan bí ogun [20] ìjọ wò, ó sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ kan pẹ̀lú ìjọ kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀méjì lọ́dún. Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ látinú ìrírí àwọn arákùnrin yìí àti ti ìyàwó wọn, tí wọ́n bá ní ìyàwó. Wọ́n máa ń sapá láti mọ tèwe tàgbà, a jọ máa ń lọ wàásù, a sì jọ máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn alábòójútó yìí àtàwọn alàgbà jọ máa ń lọ ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn àsọyé tó ń gbéni ró láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.—Ìṣe 15:35.

Wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn. Àwọn alábòójútó àyíká máa ń wá bí ìjọ ṣe máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ṣàyẹ̀wò bí wọ́n ti ń ṣe dáadáa sí, wọ́n sì máa ń fún wọn ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ nípa bí wọ́n ṣe lè bójú tó iṣẹ́ wọn. Wọ́n máa ń ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, wọ́n tún máa ń fẹ́ mọ àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé kí wọ́n sì gbọ́ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí ló ń yọ̀ǹda ara wọn láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ire [wa].” (2 Kọ́ríńtì 8:23) Ó yẹ kí a máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsin wọn sí Ọlọ́run.—Hébérù 13:7.

  • Kí nìdí tí àwọn alábòójútó àyíká fi máa ń bẹ àwọn ìjọ wò?

  • Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò wọn?