Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 24

Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?

Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?

Orílẹ̀-èdè Nepal

Orílẹ̀-èdè Tógò

Gẹ̀ẹ́sì

Ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Bíbélì àti àwọn ìwé míì lọ́dọọdún, a sì ń pín wọn fún àwọn èèyàn láì díye lé e. À ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì ń tún wọn ṣe. À ń ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí wọ́n jẹ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì, a sì ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù. Nítorí náà, o lè máa rò pé, ‘Ibo la ti ń rówó ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí?’

A kì í san ìdámẹ́wàá, a kì í bu owó fúnni tàbí gbégbá owó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó kékeré kọ́ la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù wa, a kì í tọrọ owó. Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ nínú ẹ̀dà kejì tó jáde pé, a gbà pé Jèhófà ni alátìlẹyìn wa àti pé a “kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni [a] kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn,” a kò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀!—Mátíù 10:8.

Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọyì iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe, wọ́n sì máa ń fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún un. Tayọ̀tayọ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lo àkókò, okun, owó wọn àtàwọn nǹkan mí ì láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kárí ayé. (1 Kíróníkà 29:⁠9) Àwọn àpótí téèyàn lè fi ọrẹ sí wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti láwọn àpéjọ wa, àwọn tó bá fẹ́ láti fi ọrẹ síbẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, èèyàn lè ṣètọrẹ lórí ìkànnì wa, jw.org/yo. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ ló máa ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa, bíi ti opó aláìní tí Jésù sọ̀rọ̀ rere nípa rẹ̀ tó fi ẹyọ owó kékeré méjì sínú ­àpótí ìṣúra ní tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 21:​1-4) Nítorí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè “ya ohun kan sọ́tọ̀” déédéé láti máa fi ṣètọrẹ “gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 16:2; 2 Kọ́ríńtì 9:7.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò máa mú kí àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ‘fi àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí bọlá fún òun’ kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ.—Òwe 3:9.

  • Kí ló mú kí ètò wa yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn mìíràn?

  • Báwo la ṣe ń lo ọrẹ àtinúwá tí àwọn èèyàn fi ń ṣètìlẹ́yìn?