Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

 Ẹ̀KỌ́ 14

Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Wà Fáwọn Aṣáájú-ọ̀nà

Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Wà Fáwọn Aṣáájú-ọ̀nà

Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ní Patterson, New York

Panama

Ọjọ́ pẹ́ tí ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ètò Ọlọ́run ṣètò ilé ẹ̀kọ́ pàtàkì fáwọn tí wọ́n ń lo gbogbo àkókò wọn láti máa fi kéde Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n bàa lè ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún.’—2 Tímótì 4:5.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà. Tí aṣáájú-ọ̀nà kan bá ti lo ọdún kan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó máa láǹfààní láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́fà kan tó ṣeé ṣe kó wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí kò ní jìnnà sí àgbègbè rẹ̀. Ilé ẹ̀kọ́ náà máa jẹ́ kó lè sún mọ́ Jèhófà, á jẹ́ kó túbọ̀ já fáfá nínú gbogbo ọ̀nà tí a fi ń wàásù, á sì jẹ́ kó máa fi ìṣòtítọ́ bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó.

Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere. A dá ilé ẹ̀kọ́ olóṣù méjì yìí sílẹ̀ láti pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí wọ́n nírìírí, tí wọ́n sì múra tán láti kúrò lágbègbè tí wọ́n ń gbé láti lọ sìn ní ibikíbi tí ètò Ọlọ́run bá ti nílò wọn. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé, “Èmi nìyí! Rán mi!” Wọ́n fìwà jọ Ajíhìnrere tó ga jù lọ tó tíì gbé láyé rí, ìyẹn Jésù Kristi. (Aísáyà 6:8; Jòhánù 7:29) Ó lè gba pé káwọn tí ètò Ọlọ́run rán lọ síbi tó jìnnà sí ìlú wọn fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn. Bí nǹkan ṣe rí níbi tí wọ́n kó lọ lè yàtọ̀ pátápátá, irú bí àṣà ìbílẹ̀, ojú ọjọ́ àti oúnjẹ. Ó sì lè pọn dandan pé kí wọ́n kọ́ èdè tuntun. Ilé ẹ̀kọ́ yìí máa jẹ́ kí àwọn àpọ́n, àwọn obìnrin tí kò lọ́kọ àti àwọn tọkọtaya tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàlélógún sí márùndínláàádọ́rin ní àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni tí wọ́n máa nílò nínú iṣẹ́ wọn. Á tún jẹ́ kí wọ́n lè máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àti ètò rẹ̀.

Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ní èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ náà, “Gílíádì” túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí.” Láti ọdún 1943 di ìsinsìnyí, a ti rán àwọn míṣọ́nnárì tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] tí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì láti lọ máa jẹ́rìí ní nǹkan bí igba [200] ilẹ̀, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí ńláǹlà. (Ìṣe 13:47) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì kọ́kọ́ dé orílẹ̀-èdè Peru, kò sí ìjọ kankan níbẹ̀, àmọ́ ní báyìí ìjọ tó wà níbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún kan. Nígbà táwọn míṣọ́nnárì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ Japan, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ kò tó mẹ́wàá, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti ju ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] lọ. Oṣù márùn-ún ni Ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì yìí, wọ́n sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá, àwọn tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí àwọn alábòójútó àyíká ló máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ táá jẹ́ kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù fẹsẹ̀ múlẹ̀, kó sì gbòòrò sí i kárí ayé.

  • Kí nìdí tá a fi ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà?

  • Àwọn wo ló lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere?