Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà kárí ayé, oríṣiríṣi ẹ̀yà la ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wa sì yàtọ̀ síra. Kí ló mú kí gbogbo wa wà níṣọ̀kan?

Kí Ni Ọlọ́run Ń Fẹ́?

Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn kárí ayé mọ ohun tí òun ń fẹ́. Kí ni Ọlọ́run fẹ́? Àwọn wo lónìí ló sì ń kọ́ àwọn èèyàn nípa ohun tí lọ́run ń fẹ́?

Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó lo mọ̀? Kí lo mọ̀ gan-an nípa wa?

Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pè Wá Ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ìdí mẹ́ta tí a fi ń jẹ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Báwo Ni A Ṣe Wá Mọ Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni?

Báwo la ṣe lè mọ̀ pé ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ òótọ́?

Kí Nìdí Tí A Fi Ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?

Kí ló mú kí ìtumọ̀ Bíbélì yìí ṣàrà ọ̀tọ̀?

Kí Lo Máa Gbádùn Láwọn Ìpàdé Wa?

A máa ń lọ sí ìpàdé láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì ká sì fún ara wa ní ìṣírí. A máa fi ọ̀yàyà kí ẹ káàbọ̀!

Àǹfààní Wo La Máa Rí Tá A Bá Ń Bá Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Kristẹni Ṣọ̀rẹ́?

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa jọ́sìn pẹ̀lú àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè jàǹfààní látinú irú àjọṣe yìí.

Kí Là Ń Kọ́ Láwọn Ìpàdé Wa?

Ṣé o fẹ́ mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ìpàdé wa? Ó dájú pé àwọn ẹ̀kọ́ àtàtà tó o máa kọ́ níbẹ̀ látinú Bíbélì máa wú ẹ lórí gan-an.

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Múra Dáadáa Nígbà Tá A Bá Ń Lọ sí Àwọn Ìpàdé Wa?

Ǹjẹ́ aṣọ tá a wọ̀ kan Ọlọ́run? Wo àwọn ìlànà tá a máa ń tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra.

Ọ̀nà Wo Ló Dáa Jù Láti Gbà Múra Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀?

Wàá jàǹfààní tó pọ̀ gan-an ní àwọn ìpàdé wa tó o bá múra ìpàdé náà sílẹ̀ kó o tó wá.

Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?

Wo bí ètò yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, kí ìdílé rẹ sì túbọ̀ wà níṣọ̀kan.

Kí Nìdí Tí A Fi Ń Lọ sí Àwọn Àpéjọ Ńlá?

A máa ń pé jọ lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún fún àwọn àpéjọ pàtàkì. Báwo lo ṣe lè jàǹfààní nígbà tó o bá wá sí irú àpéjọ bẹ́ẹ̀?

Báwo La Ṣe Ṣètò Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run?

A tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó wà láyé. Àwọn ọ̀nà wo là ń gbà wàásù?

Àwọn Wo Ni Aṣáájú-Ọ̀nà?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa ń fi ọgbọ̀n wákàtí, àádọ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ wàásù lóṣooṣù. Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Wà fún Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà

Ìdálẹ́kọ̀ọ́ àrà ọ̀tọ̀ wo ló wà fún àwọn tí wọ́n ń fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn kéde Ìjọba Ọlọ́run?

Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?

Àwọn alàgbà jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, wọ́n sì ń mú ipò iwájú nínú ìjọ. Ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n ń ṣe?

Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

Ohun táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń bójú tó máa ń jẹ́ kí nǹkan lọ déédéé nínú ìjọ. Kọ́ nípa bí iṣẹ́ wọn ṣe ń ṣe àwọn tó ń wá sípàdé láǹfààní.

Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?

Kí nìdí tí àwọn alábòójútó àyíká fi máa ń bẹ àwọn ìjọ wò? Kí lo lè ṣe láti jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò wọn?

Báwo La Ṣe Ń Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Ará Wa Tí Àjálù Bá?

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la máa ń ṣètò ìrànwọ́ tó máa mú kí ara tu àwọn ará wa tí àjálù bá. Lọ́nà wo?

Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?

Jésù ṣèlérí pé òun máa yan ẹrú kan láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò tó yẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun. Ọ̀nà wo ló gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

Ọ̀nà Wo Ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí Gbà Ń Ṣiṣẹ́ Lóde Òní?

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn àgbà ọkùnrin mélòó kan àtàwọn àpọ́sítélì ló para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí tí wọ́n ń bójú tó àwọn ìjọ. Lónìí ńkọ́?

Ibo Là Ń Pè Ní Bẹ́tẹ́lì?

Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ibi àrà ọ̀tọ̀ kan tó ní ìdí pàtàkì tí a fi kọ́ ọ. Mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

Kí Là Ń Ṣe ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fí ìsì Wa?

A máa ń mú àwọn àlejò káàkiri ẹ̀ka ọ́fí ìsì wa, kí wọ́n lè rí ohun tí à ń ṣe níbẹ̀. A pè ọ́ pé kí o wá!

Báwo La Ṣe Ń Kọ Àwọn Ìwé Wa, Tí A sì Ń Túmọ̀ Wọn?

À ń tẹ ìwé jáde ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (750). Kí nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?

Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ẹ̀sìn yòókù tó bá dọ̀rọ̀ bá a ṣe ń rí owó?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Báwo La sì Ṣe Ń Kọ́ Wọn?

Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń pe ilé ìjọsìn wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba? Mọ púpọ̀ sí i nípa bí àwọn ibi ìjọsìn tó mọ níwọ̀n yìí ṣe ń ran ìjọ lọ́wọ́.

Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?

Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a tọ́jú, tó sì bójú mu máa ń fìyìn fún Ọlọ́run. Ètò wo làwọn ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe láti tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn?

Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Ǹjẹ́ o fẹ́ ṣe àwọn ìwádìí kan kí ìmọ̀ rẹ nínú Bíbélì lè pọ̀ sí i? Lọ ṣèwádìí níbi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba!

Kí Ló Wà Lórí Ìkànnì Wa?

O lè mọ púpọ̀ sí i nípa wa àtohun tá a gbà gbọ́, wàá sì tún rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ nípa Bíbélì.

Ṣé Wàá Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà?

Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ojoojúmọ́ ayé rẹ?