Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀

 APÁ KEJÌ

Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín

Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín

“Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”Máàkù 10:9

Jèhófà fẹ́ kí a fọwọ́ pàtàkì mú ‘ṣíṣe òtítọ́.’ (Míkà 6:8, Bíbélì Mímọ́) Èyí ṣe pàtàkì gan-an láàárín tọkọtaya torí pé tí ẹ kò bá jẹ́ olóòótọ́ sí ara yín, ẹ kò ní lè fọkàn tán ara yín. Tí ẹ kò bá sì fọkàn tán ara yín, ìfẹ́ ò ní lè jọba láàárín yín.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kì í jẹ́ kó rọrùn fún tọkọtaya láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. O ní láti pinnu pé wàá ṣe ohun méjì kan kí o lè dáàbò bo àjọṣe àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ.

 1 FỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Máa “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Àjọṣe àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ní ìgbésí ayé rẹ. Ó wà lára ohun tó yẹ kí o kọ́kọ́ máa rò.

Jèhófà kò fẹ́ kí ohunkóhun gbé ọkàn rẹ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ, ó fẹ́ kí ẹ jọ máa “gbádùn ìgbésí ayé.” (Oníwàásù 9:9) Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé kò yẹ kí o pa ọkọ tàbí aya rẹ tì láé, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì máa wá bí ẹ ó ṣe máa mú inú ara yín dùn. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Jẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ mọ̀ pé òun wúlò gan-an, o sì mọyì òun.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Rí i dájú pé ẹ jọ ń wà pa pọ̀ déédéé. Má sì jẹ́ kí ohun míì gbà ẹ́ lọ́kàn nígbà tí ẹ bá jọ wà

  • Má ṣe máa ronú nípa ara rẹ nìkan, ti ẹ̀yin méjèèjì ni kí o máa rò

 2 MÁA ṢỌ́ ỌKÀN RẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin pẹ̀lú èrò láti bá a lò pọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀.’ (Mátíù 5:28, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀) Tí ẹnì kan bá ń ronú nípa ìṣekúṣe ṣáá, a lè sọ pé kò jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ̀.

Jèhófà sọ pé ó yẹ kí o máa ‘ṣọ́ ọkàn rẹ.’ (Òwe 4:23; Jeremáyà 17:9) Tí o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ohun tí ò ń fi ojú rẹ wò. (Mátíù 5:29, 30) Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ baba ńlá náà Jóòbù, tó bá ojú ara rẹ̀ dá májẹ̀mú pé òun kò ní tẹjú mọ́ obìnrin láti bá a ṣe ìṣekúṣe láé. (Jóòbù 31:1) Pinnu pé o kò ní wo àwòrán oníhòòhò. Má sì ṣe fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ mọ́ra.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì rí i kedere pé o kì í fi ọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ ṣeré rárá

  • Máa fiyè sí bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára ọkọ tàbí aya rẹ, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kí o fòpin sí àjọṣe ìwọ àti ẹni tí kò bá ti bá ẹnì kejì rẹ lára mu

Mọ Púpọ̀ Sí I

JÍ!

Bí Ìfẹ́ Yín Ṣe Lè Jinlẹ̀ Sí I

Ṣé ìfẹ́ tó o ní fún ọkọ tàbí aya rẹ mú kí ìdílé yín dúró sán-ún?