“Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”Sáàmù 127:3

Ọmọ bíbí máa ń múnú tọkọtaya dùn gan-an, ó sì tún máa ń gbé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́. Tí ẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ó lè yà yín lẹ́nu láti mọ̀ pé ìtọ́jú ọmọ tuntun ló máa ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò àti okun yín. Ìyípadà nínú bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára yín àti àìsùn lè dá ìṣòro sílẹ̀ láàárín yín. Àfi kí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, kí ẹ lè bójú tó ọmọ yín, kí ẹ sì lè túbọ̀ ṣera yín lọ́kan. Báwo ni ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ràn yín lọ́wọ́, kí ẹ lè wá nǹkan ṣe sí àwọn ìṣòro yìí?

 1 Ẹ FÒYE MỌ ÌYÍPADÀ TÍ ỌMỌ MÚ WÁ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere.” Ó tún sọ pé, ìfẹ́ “kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Nígbà tí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ó dájú pé ọ̀dọ̀ ọmọ rẹ ni ọkàn rẹ á máa fà sí jù. Àmọ́, ọkọ rẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pé ò ń pa òun tì, torí náà má gbàgbé pé ó yẹ kí ọkàn rẹ máa fà sí ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ pẹ̀lú. Tí o bá ní sùúrù tí o sì ń fi hàn pé o láàánú ọkọ rẹ, wàá lè fi hàn pé o nílò rẹ̀, ẹ ó sì lè jọ máa bójú tó ọmọ yín.

“Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé . . . ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀.” (1 Pétérù 3:7) Máa fi sọ́kàn pé àbójútó ọmọ ló máa gba èyí tó pọ̀ jù nínú okun ìyàwó rẹ. Ojúṣe tuntun ló délẹ̀ yìí, ó sì lè fa másùnmáwo àti ìdààmú ọkàn tàbí kó tiẹ̀ tán an lókun pàápàá. Kódà nígbà míì, ó lè kanra mọ́ ẹ, àmọ́ sùúrù ni kó o ṣe, torí pé “ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.” (Òwe 16:32) Máa fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, kí o sì máa ràn án lọ́wọ́ bó ṣe yẹ.Òwe 14:29.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ̀yin Bàbá: Ẹ máa ran ìyàwó yín lọ́wọ́ láti tọ́jú ọmọ, ì báà jẹ́ láàárín òru pàápàá. Ẹ dín àkókò tí ẹ̀ ń lò nídìí àwọn nǹkan míì kù, kí ẹ lè túbọ̀ ráyè gbọ́ ti ìyàwó àti ọmọ yín

  • Ẹ̀yin Ìyá: Tí ọkọ yín bá fẹ́ ràn yín lọ́wọ́ láti tọ́jú ọmọ, ẹ jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Tí kò bá mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ sí i, ṣe ni kí ẹ fi sùúrù ṣàlàyé bó ṣe máa ṣe é fún un

 2 Ẹ TÚBỌ̀ ṢERA YÍN LỌ́KAN

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Wọn yóò sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Òótọ́ ni pé ẹni tuntun kan ti kún yín nínú ìdílé yín báyìí, síbẹ̀ má gbàgbé pé “ara kan” ni ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ṣì jẹ́. Torí náà, ṣe ni kí ẹ̀yin méjèèjì sa gbogbo ipá yín kí ẹ lè túbọ̀ ṣera yín lọ́kan.

Ẹ̀yin aya, ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọkọ yín pé wọ́n ń ràn yín lọ́wọ́, wọ́n sì ń tì yín lẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ ìmoore tí ẹ bá ń sọ lè dà bí “ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa sọ fún àwọn aya yín bí ẹ ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn àti bí ẹ ṣe mọyì wọn tó. Ẹ máa yìn wọ́n torí pé wọ́n ń tọ́jú ìdílé yín.Òwe 31:10, 28.

“Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Ohun tó bá dára jù ni kí o máa ṣe fún ọkọ tàbí aya rẹ. Ó yẹ kí ẹ̀yin tọkọtaya máa wá àyè láti jọ sọ̀rọ̀, kí ẹ máa gbóríyìn fún ara yín, kí ẹ sì máa tẹ́tí gbọ́rọ̀ ara yín. Má ṣe máa ro tara rẹ nìkan tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Máa ronú nípa ohun tí ẹnì kejì rẹ fẹ́ pẹ̀lú. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa fi du ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, àyàfi nípasẹ̀ àjọgbà.” (1 Kọ́ríńtì 7:3-5) Torí náà, ó yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ yìí láìfi ohunkóhun pa mọ́ fún ara yín. Tí ẹ bá ń ní sùúrù fún ara yín, tí ẹ sì ń lo òye, ẹ ó lè túbọ̀ ṣera yín lọ́kan.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa wá àyè tí ẹ̀yin méjèèjì nìkan á fi jọ máa wà pa pọ̀

  • Máa ṣe àwọn ohun kéékèèké tó máa mú kí ẹnì kejì rẹ mọ̀ pé o fẹ́ràn òun. O lè kọ̀wé ṣókí sí i tàbí kí o ra ẹ̀bùn kékeré fún un

 3 BÍ Ẹ ṢE MÁA TỌ́ ỌMỌ YÍN

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Tímótì 3:15) Ẹ ṣètò àwọn ohun tí ẹ máa ṣe láti kọ́ ọmọ yín. Àwọn ọmọ lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó yani lẹ́nu gan-an, kódà láti inú oyún pàápàá. Látinú oyún ni ọmọ rẹ ti dá ohùn rẹ mọ̀, ó sì máa ń dáhùn pa dà sí bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí lára rẹ. Ẹ máa kàwé sí i létí kódà nígbà tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́. Bí kò bá tiẹ̀ lóye ohun tí ẹ̀ ń kà, ó máa jẹ́ kó gbádùn ìwé kíkà nígbà tó bá dàgbà.

Ọmọ yín kò fìgbà kan kéré jù láti gbọ́ ohun tí ẹ bá ń sọ nípa Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kó máa tẹ́tí sí yín tí ẹ bá ń gbàdúrà sí Jèhófà. (Diutarónómì 11:19) Kódà bí ẹ bá jọ ń ṣeré, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. (Sáàmù 78:3, 4) Bí ọmọ yín ṣe ń dàgbà, ó máa kíyè sí ìfẹ́ tí ẹ ní sí Jèhófà, èyí sì máa kọ́ òun náà láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Bẹ Jèhófà pé kó fún ọ ní ọgbọ́n tí wàá lè fi tọ́ ọmọ rẹ

  • Máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kókó àti àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì lásọtúnsọ fún ọmọ rẹ, kó lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ láti kékeré