Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

MO dagba ni abule kekere kan ni ẹkun ipinlẹ iha ariwa,” ni Dauda lati Sierra Leone rohin. “Nigba kan, nigba ti mo wa ni kekere, ariyanjiyan lori ilẹ ṣẹlẹ laaarin idile mi ati idile miiran. Awọn mejeeji sọ pe ilẹ naa jẹ tiwọn. Ọgbẹni oniṣegun kan ni a pè wá lati yanju ọran naa. Oun fun ọkunrin kan ni jiigi kan, o si fi aṣọ funfun kan bò ó. Laipẹ ọkunrin ti o wà labẹ aṣọ naa bẹrẹsii gbọ̀n o sì nlaagun. Oun kigbe jade bi o ti wo inu jiigi naa pe: ‘Mo ri baba agbalagba kan nbọwa! O wọ aṣọ funfun. O ga o si jẹ arugbo, pẹlu ewú lórí, o sì nrin pẹlu ẹhin rẹ̀ ti o tẹ̀ba.’

“Oun nṣapejuwe baba agba! Lẹhin naa o di onigboonara o sì ke jade pe: ‘Ẹ wa wò ó funraayin bi ẹyin kò ba gba ohun ti mo nsọ gbọ!’ Bi o tilẹ ri bẹẹ, ko si ẹnikẹni ninu wa ti o ni igboya lati ṣe bẹẹ! Ọgbẹni oniṣegun naa mu ki ara ọkunrin naa wálẹ̀ nipa wíwọ́n àpòpọ̀ ewé ati omi onídán si i lara, eyi ti o gbe dani ninu igbá kan.

“Ni gbigba ẹnu ọkunrin ti o nwo jiigi naa sọrọ, ‘baba agba’ sọ pe ilẹ naa jẹ ti idile wa. O sọ fun iya agba pe ki o maa ṣiṣẹ lori ilẹ naa lọ falala. Idile keji tẹwọgba idajọ naa. Ariyanjiyan naa si yanju.”

 Iru awọn iriri bawọnyi wọpọ ni Iwọ-oorun Africa. Nihin-in, bii awọn apa miiran ninu aye, ọpọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan gbagbọ pe awọn oku nrekọja si ilẹ ẹmi, nibi ti wọn ti le ṣakiyesi ki wọn si nipa lori awọn eniyan ti wọn walaaye lori ilẹ-aye. Igbagbọ yii ha jẹ ootọ bi? Awọn oku ha walaaye niti gidi bi? Bi ko ba ri bẹẹ, awọn wo ni wọn dibọn bi ẹmi oku awọn ẹni ti o ti ku? Mimọ idahun ti o tọna si awọn ibeere wọnyi ṣe pataki niti gidi. O jẹ ọran ìyè ati ikú.