Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?

Awọn Ẹmi Ko Gbe Ki Wọn si Kú Rí Lori Ilẹ Aye

Awọn Ẹmi Ko Gbe Ki Wọn si Kú Rí Lori Ilẹ Aye

Awọn ẹmi wà! Awọn ẹmi rere ati buburu ni o wà ni ilẹ akoso ẹmi. Wọn ha jẹ awọn eniyan ti wọn ti gbe laye ti wọn si ti ku lori ilẹ-aye bi?

Rara, wọn kii ṣe bẹẹ. Nigba ti ẹnikan ba ku, oun ko rekọja lọ si ilẹ-ọba ẹmi, gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn eniyan ti rò. Bawo ni a ṣe mọ eyi? Nitori pe Bibeli sọ bẹẹ. Bibeli jẹ iwe otitọ ti o wá lati ọdọ Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, ẹni ti orukọ rẹ̀ njẹ Jehofa. Jehofa ṣẹ̀dá awọn eniyan; o sì mọ̀ daradara ohun ti o nṣẹlẹ si wọn nigba ti wọn ba ku.—Saamu 83:18; 2 Timoti 3:16.

Adamu wá lati inu erupẹ, o si pada si erupẹ

Bibeli sọ pe Ọlọrun ṣẹ̀dá Adamu, ọkunrin akọkọ, “lati inu erupẹ ilẹ.” (Jẹnẹsisi 2:7, NW) Ọlọrun fi i sinu Paradise, ọgba Edeni. Bi Adamu ba ti ṣegbọran si ofin Jehofa, oun ki ba ti ku; oun ìbá ṣi walaaye lori ilẹ-aye lonii. Ṣugbọn nigba ti Adamu mọọmọ ru ofin Ọlọrun, Ọlọrun sọ fun un pe: “Iwọ yoo pada si ilẹ; nitori inu rẹ̀ ni a ti mu ọ wa, erupẹ saa ni iwọ, iwọ yoo si pada di erupẹ.—Jẹnẹsisi 3:19.

Ki ni eyi tumọsi? Tóò, nibo ni Adamu wà ṣaaju ki Jehofa to ṣẹ̀dá rẹ̀ lati inu erupẹ? Ko si ni ibikibi. Oun kii ṣe ẹmi ti a kò tii bi ni ọrun. Oun kò wà rara. Nitori naa nigba ti Jehofa sọ pe Adamu “yoo pada si erupẹ,” o ní in lọkan pe Adamu yoo ku. Oun ko rekọja lọ si ilẹ-akoso ẹmi. Nigba ti o ku, Adamu lẹẹkan sii di alailẹmii, alaisi. Iku jẹ aisi ìyè.

Ṣugbọn ki ni nipa ti gbogbo awọn wọnni ti wọn ti ku?  Awọn bakan naa ha jẹ alaisi bi? Bibeli dahun pe:

  • “[Eniyan ati ẹranko] nibi kan naa ni gbogbo wọn nlọ; lati inu erupẹ wa ni gbogbo wọn, gbogbo wọn sì tun pada di erupẹ.”—Oniwaasu 3:20.

  • “Awọn oku . . . kò mọ ohun kan.”—Oniwaasu 9:5.

  • “Ifẹ wọn pẹlu, ati irira wọn, ati ilara wọn, o parun nisinsinyi.”—Oniwaasu 9:6.

  • “Ko si ète, bẹẹ ni kò si ìmọ̀, tabi ọgbọ́n, ni isà-òkú nibi ti iwọ ńrè.”—Oniwaasu 9:10.

  • “[Eniyan] pada si erupẹ rẹ̀; ni ọjọ naa gan-an, iro inu rẹ̀ run.”—Saamu 146:4.

Kiki awọn alaaye ni wọn le ṣe awọn nnkan wọnyi

Awọn ẹsẹ iwe mimọ wọnyi ha ṣòro fun ọ lati gbàgbọ́ bi? Bi o ba ri bẹẹ, ronu lori eyi: Ninu ọpọlọpọ idile, ọkunrin ni o nṣiṣẹ owó lati ṣetilẹhin fun agbo ile rẹ̀. Nigba ti ọkunrin naa ba ku, idile rẹ̀ saba maa njiya inira. Nigba miiran iyawo ati awọn  ọmọ rẹ̀ le ma tilẹ ni owo tí o to lati ra ounjẹ. Awọn ọta ọkunrin naa lè lò wọn ni ilokulo paapaa. Beere lọwọ araarẹ nisinsinyi: ‘Bi ọkunrin naa ba walaaye ni ilẹ akoso ẹmi, eeṣe ti oun kò fi maa baa lọ lati pese fun idile rẹ̀? Eeṣe ti oun kò fi daabobo idile rẹ̀ lọwọ awọn eniyan buburu?’ O jẹ nitori pe iwe mimọ tọ̀nà. Ọkunrin naa jẹ alailẹmii, alaile ṣe ohunkohun.—Saamu 115:17.

Awọn oku kò lè ran awọn ẹni ti ebi npa lọwọ tabi daabobo awọn ti a njẹniya

Eyiini ha tumọsi pe awọn oku ki yoo wá si aaye lẹẹkan sii bi? Rara, ko ri bẹẹ. Awa yoo sọrọ nipa ajinde ni iwaju. Ṣugbọn o tumọsi pe awọn oku kò mọ ohun ti iwọ nṣe. Wọn kò lè rí ọ, gbọ́ ọ, tabi bá ọ sọrọ. Kò si idi fun ọ lati bẹru wọn. Wọn kò lè ran ọ lọwọ, wọn kò sì lè pa ọ lara.—Oniwaasu 9:4; Aisaya 26:14.