Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?

Awọn Ẹmi-eṣu Fun Iṣọtẹ Lodisi Ọlọrun Ni Iṣiri

Awọn Ẹmi-eṣu Fun Iṣọtẹ Lodisi Ọlọrun Ni Iṣiri

Awọn àṣà kan ni a gbe kari irọ́ naa pe awọn oku lè rí wa

Ṣugbọn eeṣe ti Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ fi nṣiṣẹ tokuntokun bẹẹ lati tan awọn eniyan jẹ? Nitori pe wọn fẹ ki a darapọ mọ́ wọn ninu iṣọtẹ wọn? Wọn fẹ ki a maa jọsin wọn. Wọn fẹ ki a gba awọn irọ́ wọn gbọ́ ki a sì maa ṣe awọn ohun ti Jehofa kò fẹ́. Ọpọ awọn iṣe wọnyi ní ninu awọn àṣà ti o nii ṣe pẹlu awọn oku.

Iku ololufẹ ẹni kan jẹ iriri imọlara ti nronilara kan. O ba iwa ẹda mu o sì tọna lati fi ibanujẹ hàn. Lẹhin iku ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lasaru, Jesu “sọkun.”—Johanu 11:35.

Ọpọlọpọ awọn àṣà ni o ní isopọ pẹlu isinku, iwọnyi sì yatọ lati ibi kan si ibi keji jakejado agbaye. Ọpọ ninu wọn ni kò forigbari pẹlu awọn ilana Bibeli. Awọn àṣà kan, bi o ti wu ki o ri, ni a gbe kari ero naa pe awọn oku walaaye wọn sì lè ri awọn alaaye. Awọn àìsùn, ọ̀fọ̀ ailaala, ati awọn aṣeyẹ oku rẹpẹtẹ ni wọn ta gbongbo ninu ibẹru àífẹ́ẹ́ṣe ohun ti yoo bí ẹmi awọn oku ninu. Ṣugbọn niwọn bi awọn òkú kò ti “mọ ohun kan,” awọn ti nṣe iru awọn nnkan bẹẹ ngbe irọ Satani ga siwaju.—Oniwaasu 9:5.

Awọn àṣà miiran ni a gbe kari irọ́ naa pe awọn oku nilo iranlọwọ wa

 Awọn àṣà tabi aṣeyẹ miiran nwa lati inu igbagbọ naa pe awọn oku nilo iranwọ lati ọdọ awọn alaaye ti wọn sì lè ṣe ipalara fun alaaye bi a kò bá tù wọn loju. Ni awọn ilẹ kan àsè ati awọn irubọ ni a nṣe yala ni ogoji ọjọ tabi ọdun kan lẹhin iku ẹnikan. Eyi ni a rò pe yoo ran olóògbé naa lọwọ lati ‘rekọja lọ’ si ilẹ akoso ẹmi. Àṣà miiran ti o tun wọpọ ni lati pese ounjẹ ati ohun mimu fun awọn oku.

Awọn nnkan wọnyi kò tọna nitori pe wọn ngbe irọ́ Satani nipa awọn oku ga siwaju. Jehofa yoo ha fọwọsi ohunkohun ti o nii ṣe pẹlu awọn àṣà ti a gbe kari ẹkọ awọn ẹmi eṣu bi? Ki a ma rii!—2 Kọrinti 6:14-18.

Awọn iranṣẹ Ọlọrun tootọ kii nípìn-ín kankan ninu àṣà ti o nti awọn irọ́ Satani lẹhin. Kaka bẹẹ, wọn fi tifẹtifẹ pọkanpọ sori riran awọn alaaye lọwọ ati titu wọn ninu. Wọn mọ̀ pe niwọn igba ti ẹnikan ba ti ku, Jehofa nikanṣoṣo ni o lè ran ẹni naa lọwọ.—Joobu 14:14, 15.

Ọlọrun Dẹbi Fun Ibẹmiilo

Awọn eniyan kan ni isopọ pẹlu awọn ẹmi-eṣu ni taarata tabi nipasẹ awọn abẹmiilo. Eyi ni a npe ni biba ẹmi lò. Iṣẹ́-oṣó, ajẹ, idán, kikiyesi igba, ati biba oku sọrọ jẹ iru oriṣi ibẹmiilo.

Ọlọrun lodisi awọn nnkan buburu wọnyi. O beere ijọsin ti a yasọtọ gedegbe si oun nikan.—Ẹkisodu 20:5

Bibeli dẹbi fun iru awọn nnkan wọnyi, ni sisọ pe: “Ki a maṣe ri ninu yin ẹnikan tí nfọ àfọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi ìgbà, tabi aṣefàyà, tabi àjẹ́, tabi atujú, tabi abá iwin gbìmọ̀, tabi oṣó, tabi abókùúlò. Nitori pe gbogbo awọn ti nṣe nnkan wọnyi irira ni si Oluwa [“Jehofa,” NW].”—Deutaronomi 18:10-12.

Eeṣe ti Jehofa fi kilọ fun wa gidigidi lodisi awọn àṣà wọnyi?

Jehofa kilọ fun wa lodisi gbogbo oriṣi ibẹmiilo fun anfaani wa. O nifẹẹ awọn eniyan o si bikita fun wọn, o sì mọ̀ pe awọn  wọnni ti wọn nba ẹmi-eṣu lò dajudaju yoo jìyà.

Iru ẹnikan bẹẹ ni Nilda, ti o jẹ abẹmiilo kan ni Brazil. Awọn ẹmi-eṣu sọ igbesi-aye rẹ̀ di rádaràda. Oun sọ pe: “Ẹmi . . . gbémi, o si ndari mi kaakiri. Mo ńdákú dájí, mo sì wa labẹ itọju iṣegun fun awọn iṣoro ọpọlọ. Awọn ẹmi-eṣu fiya jẹ mi tobẹẹ ti o fi kan awọn iṣan imọlara mi. Mo lo awọn oogun akunniloorun mo si bẹrẹsii mutí ati sìgá leralera. Eyi nbaa lọ fun ọpọlọpọ ọdun.”

Awọn ti wọn nlọwọ ninu ibẹmiilo saba maa nba laburu pade. Wọn le padanu ile wọn, ominira wọn, ani iwalaaye wọn paapaa

Nigba ti o ṣe, pẹlu iranlọwọ Jehofa ati awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lori ilẹ-aye, Nilda ja àjàbọ́ kuro lọwọ idari awọn ẹmi-eṣu o si ngbe igbesi-aye ọlọ́rọ̀, ti o gbámúṣe nisinsinyi. Oun wi pe: “Mo gba gbogbo eniyan niyanju lati maṣe, darapọ bi o ba tilẹ jẹ fun akoko diẹ, pẹlu awọn ẹmi [buburu].”