Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 23

Wọ́n Ṣèlérí fún Jèhófà

Wọ́n Ṣèlérí fún Jèhófà

Wọ́n Ṣèlérí fún JèhófàNí nǹkan bí oṣù méjì lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọ́n dé Òkè Sínáì, wọ́n sì pàgọ́ síbẹ̀. Jèhófà pe Mósè, Mósè sì lọ sí orí òkè náà. Jèhófà sọ fún un pé: ‘Mo ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là. Àmọ́ bí wọ́n bá gbọ́ràn sí mi lẹ́nu tí wọ́n sì pa òfin mi mọ́, wọ́n yóò di èèyàn mi.’ Mósè sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè náà, ó sì lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí ni àwọn èèyàn náà sọ? Wọ́n ní: ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ fún wa la máa ṣe.’

Mósè tún pa dà sórí òkè náà. Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Mo máa bá yín sọ̀rọ̀ ní ojọ́ mẹ́ta sí i. Àmọ́, kìlọ̀ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n má ṣe wá sórí Òkè Sínáì.’ Mósè sì lọ jíṣẹ́ fún wọn pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.

Nígbà tó di ọjọ́ kẹta, òkùnkùn bo orí òkè náà, mọ̀nàmọ́ná sì ń kọ mọ̀nà. Wọ́n tún gbọ́ ìró fèrè àti àrá tó ń sán gan-an. Jèhófà sì sọ̀ kalẹ̀ sórí òkè náà nínú iná. Èyí mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gidigidi. Òkè náà mì tìtì, èéfín sì bò ó. Ìró fèrè náà wá ń lọ sókè sí i. Ọlọ́run wá sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni Jèhófà. Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run mìíràn.’

Mósè pa dà lọ sórí òkè náà. Jèhófà sì fún un ní òfin tó dá lórí bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn òun àti ìwà tí wọ́n á máa hù. Mósè kọ òfin náà sílẹ̀, ó sì kà á fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọ́n wá ṣèlérí pé: ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ fún wa la máa ṣe.’ Wọ́n ti ṣèlérí fún Ọlọ́run báyìí, ṣùgbọ́n ṣé wọ́n máa mú ìlérí wọn ṣẹ?

“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” ​—Mátíù 22:37

Mọ Púpọ̀ Sí I

KÁÀDÌ ERÉ BÍBÉLÌ

Káàdì Eré Bíbélì Nípa Mósè

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Mósè lẹni àkọ́kọ́ tó ṣe iṣẹ́ ìyànu nínú Bíbélì? Wa káàdì eré Bíbélì yìí jáde kó o lè mọ púpọ̀ sí i.