Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 24

Wọn Kò Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ

Wọn Kò Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ

Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Wá bá mi lórí òkè. Kí n lè kọ àwọn òfin mi sórí òkúta pẹlẹbẹ fún ẹ.’ Mósè gun orí òkè náà lọ, ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì [40] ọjọ́ àti ogójì [40] òru. Ní gbogbo àsìkò yẹn, Jèhófà kọ Òfin Mẹ́wàá náà sórí òkúta pẹlẹbẹ méjì, ó sì gbé e fún Mósè.

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tètè rí Mósè, wọ́n ronú pé Mósè ti pa àwọn tì. Wọ́n bá sọ fún Áárónì pé: ‘A fẹ́ kí ẹnì kan máa darí wa. Ṣe ọlọ́run kan fún wa!’ Áárónì wá sọ pé: ‘Ẹ kó àwọn góòlù yín wá.’ Ó fi iná yọ́ góòlù náà, ó sì fi ṣe ère màlúù. Àwọn èèyàn náà sọ pé: ‘Ère yìí ni Ọlọ́run wa tó kó wa jáde nílẹ̀ Íjíbítì!’ Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ère náà, wọ́n sì ń ṣe àríyá. Ṣé ohun tí wọ́n ṣe yìí burú àbí kò burú? Ó burú torí pé àwọn èèyàn náà ti ṣèlérí pé Jèhófà nìkan ni àwọn máa jọ́sìn. Àmọ́, wọn kò mú ìlérí wọn ṣẹ.

 Jèhófà rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì sọ fún Mósè pé: ‘Sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn èèyàn náà. Wọ́n ti ṣàìgbọràn sí mi, wọ́n sì ti ń bọ òrìṣà.’ Mósè sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú àwọn òkúta pẹlẹbẹ méjì tó wà lọ́wọ́ rẹ̀.

Bó ṣe ń sún mọ́ ibi tí àwọn èèyàn náà wà, ó gbọ́ tí wọ́n ń kọrin. Ó tún rí wọn tí wọ́n ń jó tí wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún ère màlúù náà. Inú bí Mósè gan-an. Ló bá la òkúta pẹlẹbẹ méjèèjì tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ pátápátá. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ba ère màlúù náà jẹ́. Ó wá bi Áárónì pé: ‘Kí ló dé tí o jẹ́ kí àwọn èèyàn yìí mú kí o hu ìwà burúkú yìí?’ Áárónì sọ pé: ‘Má bínú. Ìwọ náà mọ ìwà àwọn èèyàn yìí. Wọ́n ní àwọn ń wá ọlọ́run, ni mo bá gba àwọn góòlù wọn, mo dà á sínú iná, bí ère màlúù yìí ṣe jáde nìyẹn!’ Kò yẹ kí Áárónì ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Mósè wá pa dà sórí òkè náà, ó sì bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wọ́n.

Jèhófà dárí ji àwọn tó ṣègbọràn nínú wọn. Ṣé ìwọ náà rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa tẹ̀ lé Mósè tó jẹ́ aṣáájú wọn?

“Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti san án, nítorí pé kò sí níní inú dídùn sí àwọn arìndìn. Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.”​—Oníwàásù 5:4

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÀWỌN ÀWÒRÁN ÌTÀN BÍBÉLÌ

Awon Omo Isireli Se Ere Omo Maluu

Awon omo Isireli se ere kan, won si so pe oun ni Olorun. Amo, se Olorun fowo si i?

ERÉ ALÁWÒRÁN

Awon Omo Isireli Se Ere Kan

Wo awon aworan yii ko o le mo iyato ninu mejeeji, ko o si kun won.