Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 27

Wọ́n Tako Jèhófà

Wọ́n Tako Jèhófà

Láàárín àsìkò tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aṣálẹ̀, Kórà, Dátánì, Ábírámù, àti àwọn 250 ọkùnrin míì tako Mósè. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Ọ̀rọ̀ rẹ ti sú wa! Ó ṣe jẹ́ pé ìwọ nìkan lo máa ń ṣe bí ọ̀gá lórí wa, ṣé Áárónì nìkan ló lè ṣe àlùfáà àgbà ni? Ìwọ àti Áárónì nìkan kọ́ ni Jèhófà wà pẹ̀lú, ó wà pẹ̀lú àwa náà.’ Inú bí Jèhófà sí ohun tí wọ́n sọ yìí. Lójú Jèhófà, ńṣe ló dà bíi pé òun ni àwọn èèyàn náà ń takò!

Mósè wá sọ fún Kórà àti àwọn èèyàn rẹ̀ tó kù pé: ‘Ẹ wá sí àgọ́ ìjọsìn ní ọ̀la, kí ẹ sì fi tùràrí sórí ìkóná yín. Jèhófà máa fi ẹni tí ó fẹ́ hàn wá.’

Lọ́jọ́ kejì, Kórà àti àwọn 250 ọkùnrin lọ pàdé Mósè ní àgọ́ ìjọsìn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sun tùràrí bíi pé àlùfáà ni wọ́n. Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì pé: ‘Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ Kórà àti àwọn èèyàn rẹ̀.’

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kórà lọ pàdé Mósè ní àgọ́ ìjọsìn. Dátánì, Ábírámù, àti ìdílé wọn kò bá wọn lọ síbẹ̀. Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n kúrò ní àyíká ibi tí Kórà, Dátánì, àti Ábírámù ń gbé.  Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Dátánì, Ábírámù, àti gbogbo ìdílé wọn wá dúró síwájú ìta ilé wọn. Lójijì, ilẹ̀ lanu ó sì gbé wọn mì! Ní àgọ́ ìjọsìn, iná yọ láti ọ̀run, ó sì jó Kórà àti àwọn 250 ọkùnrin run.

Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: ‘Gba ọ̀pá kan lọ́wọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí ọ̀pá tirẹ̀. Ṣùgbọ́n Áárónì ni kí o kọ sára ọ̀pá ti ẹ̀yà Léfì. Kó àwọn ọ̀pá yìí sínú àgọ́ ìjọsìn, ọ̀pá ẹni tí mo bá sì yàn máa yọ òdòdó.’

Nígbà tó di ọjọ́ kejì, Mósè kó àwọn ọ̀pá náà jáde láti fi han àwọn olórí náà. Ọ̀pá Áárónì ló yọ òdòdó, ó sì tún ní èso álímọ́ńdì tó ti pọ́n. Jèhófà tipa báyìí fi dá wọn lójú pé Áárónì ni òun yàn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà.

“Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.”​—Hébérù 13:17