Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 25

Wọ́n Kọ́ Àgọ́ Ìjọsìn

Wọ́n Kọ́ Àgọ́ Ìjọsìn

Nígbà tí Mósè wà lórí Òkè Sínáì, Jèhófà ní kí ó kọ́ àgọ́ kan tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ti máa jọ́sìn òun. Wọ́n á sì máa gbé àgọ́ náà lọ sí gbogbo ibi tí wọ́n bá fẹ́ lọ.

Jèhófà sọ pé: ‘Sọ fún àwọn èèyàn náà pé ohunkóhun tí agbára wọn bá gbé ni kí wọ́n mú wá fún kíkọ́ àgọ́ náà.’ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú góòlù, fàdákà, bàbà, àwọn òkúta iyebíye àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wá. Wọ́n tún mú òwú, aṣọ ọ̀gbọ̀, awọ ẹran àti àwọn nǹkan míì wá. Ohun tí wọ́n mú wá pọ̀ débi tí Mósè fi sọ fún wọn pé: ‘Ohun tí ẹ mú wá ti tó! Ẹ má ṣe mú ohunkóhun wá mọ́.’

Àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí wọ́n mọ iṣẹ́ ló kọ́ àgọ́ náà. Jèhófà tún fún wọn ní ọgbọ́n láti ṣe iṣẹ́ náà. Àwọn kan ń ran òwú, àwọn míì sì ń hun aṣọ. Àwọn míì ń to òkúta, wọ́n ń fi góòlù ṣe oríṣiríṣi nǹkan, wọ́n sì ń gbẹ́ igi.

Àwọn èèyàn náà kọ́ àgọ́ náà gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n kọ́ ọ. Wọ́n ṣe aṣọ ìkélé tó rẹwà gan-an láti fi pín àgọ́ náà sí méjì, kó lè pààlà sí Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú sí. Igi àti góòlù ni wọ́n fi ṣe é. Ọ̀pá fìtílà tí wọ́n fi góòlù ṣe, tábìlì kan àti pẹpẹ tí wọ́n ti ń sun tùràrí wà nínú Ibi Mímọ́. Báàfù bàbà kan àti pẹpẹ ńlá kan sì wà nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì náà. Tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá tí ń rí àpótí májẹ̀mú yìí, wọ́n máa ń rántí ìlérí tí wọ́n ṣe fún Jèhófà láti máa ṣègbọràn sí i. Ṣé o mọ ohun tí májẹ̀mú túmọ̀ sí?  Májẹ̀mú jẹ́ ìlérí àrà-ọ̀tọ̀ kan tí èèyàn gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ pàtàkì mú.

Jèhófà yan Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti máa ṣisẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú àgọ́ yìí. Wọ́n ní láti máa bójú tó ibẹ̀, kí wọ́n sì máa rúbọ sí Jèhófà níbẹ̀. Áárónì tó jẹ́ àlùfáà àgbà nìkan ló ní ẹ̀tọ́ láti wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ló sì máa ń wọ ibẹ̀, ohun tó sì máa ń gbé lọ síbẹ̀ ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀, ti àwọn ẹbí rẹ̀ àti ti gbogbo ìlú Ísírẹ́lì lápapọ̀.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ àgọ́ náà parí lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n kúrò ní ìlú Íjíbítì. Ní báyìí, wọ́n ti wá ní ibi tí wọ́n á ti máa jọ́sìn Jèhófà.

Jèhófà jẹ́ kí ògo rẹ̀ bo àgọ́ náà, ó sì tún mú kí àwọsánmà yọ lórí àgọ́ ìjọsìn yìí. Bí wọ́n bá ń rí àwọsánmọ̀ yẹn lórí àgọ́ náà, wọn kò ní kúrò níbi tí wọ́n wà, àmọ́ tí àwọsánmọ̀ náà bá sún sókè, wọ́n mọ̀ pé àkókò ti tó láti gbéra kúrò níbi tí wọ́n dúró sí. Wọ́n á tú àgọ́ ìjọ́sìn náà palẹ̀, wọ́n á sì máa tẹ̀ lé àwọsánmà náà lẹ́yìn.

“Pẹ̀lú ìyẹn, mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn.’ ”​—Ìṣípayá 21:3