Apá yìí máa jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀dọ́, àwọn wòlíì àti àwọn ọba tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Ní ilẹ̀ Síríà, ọmọbìnrin kékeré kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbàgbọ́ pé wòlíì Jèhófà máa wo Náámánì sàn. Wòlíì Èlíṣà ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà máa gba òun lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀tá. Jèhóádà Àlùfáà Àgbà fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó lè dáàbò bo Jèhóáṣì lọ́wọ́ Ataláyà ìyá rẹ̀ àgbà tó fẹ́ pa á. Ẹ̀rù kò ba Ọba Hesekáyà nígbà tí àwọn ará Ásíríà ń halẹ̀ mọ́ ọn torí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì mọ̀ pé ó máa gba àwọn là. Ọba Jòsáyà fi òpin sí bíbọ òrìṣà, ó tún tẹ́ńpìlì ṣe, ó sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jọ́sìn Jèhófà pa dà.