Jèhófà bù kún Sólómọ́nì gan-an, ó fún un ní ọgbọ́n, ó sì jẹ́ kó kọ́ tẹ́ńpìlì fún òun. Àmọ́ nígbà tó yá, Sólómọ́nì fi Jèhófà sílẹ̀. Tí o bá jẹ́ òbí, ṣàlàyé fún ọmọ rẹ bí ìjọsìn òrìṣà ṣe mú kí Sólómọ́nì fi Jèhófà sílẹ̀. Ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì, àwọn ọba búburú tó sì jẹ mú kí àwọn èèyàn náà máa jọ́sìn òrìṣà. Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì Jèhófà ni wọ́n fìyà jẹ tí wọ́n sì pa. Jésíbẹ́lì tó jẹ́ ayaba tún mú kí àwọn èèyàn jọ́sìn àwọn òrìṣà burúkú. Nǹkan burú gan-an fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkókò yìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lásìkò yẹn. Lára wọn ni Ọba Jèhóṣáfátì àti wòlíì Èlíjà.