Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 39

Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

Jèhófà yan àwọn onídàájọ́ láti darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ ní báyìí, wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ ní ọba. Wọ́n sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wa ló ní ọba. Àwa náà fẹ́ ní ọba.’ Sámúẹ́lì ronú pé ohun tí wọ́n béèrè yìí kò dára, torí náà ó gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Èmi ni àwọn èèyàn yìí ò fẹ́, kì í ṣe ìwọ. Sọ fún wọn pé wọ́n máa ní ọba, àmọ́ ọba náà máa gba ohun tó pọ̀ lọ́wọ́ wọn.’ Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà sọ pé: ‘Ó tẹ́ wa lọ́rùn, ṣáà fún wa ní ọba!’

Jèhófà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù ló máa jẹ́ ọba àkọ́kọ́. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù lọ kí Sámúẹ́lì ní ìlú Rámà, Sámúẹ́lì ta òróró sí i lórí láti fi hàn pé òun ti yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba.

Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ láti fi ẹni tó máa jẹ́ ọba hàn wọ́n. Àmọ́, wọ́n wá Sọ́ọ̀lù títí, wọn kò rí i. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á? Ìdí ni pé ńṣe ló lọ sá pa mọ́ sí àárín àwọn ẹrù. Nígbà tí wọ́n wá rí Sọ́ọ̀lù, wọ́n mú un jáde, wọ́n sì ní kó dúró síwájú àwọn èèyàn náà. Sọ́ọ̀lù ga ju gbogbo wọn lọ, ó sì lẹ́wà. Sámúẹ́lì wá sọ pé: ‘Ẹni tí Jèhófà yàn fún un yín rè é o.’ Gbogbo wọn bá pariwo pé: ‘Kábíyèsí o!’

Níbẹ̀rẹ̀, Ọba Sọ́ọ̀lù máa ń gbọ́ràn sí Sámúẹ́lì lẹ́nu, ó sì ń pa àṣẹ Jèhófà mọ́. Àmọ́, nígbà tó yá, kò hùwà dáadáa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọba kò lẹ́tọ̀ọ́ láti rúbọ sí Jèhófà. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé kó dúró de òun, ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì kò tètè dé. Ni Sọ́ọ̀lù bá rú ẹbọ náà fúnra rẹ̀. Kí ni Sámúẹ́lì ṣe nígbà tó dé? Ó sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: ‘Kò yẹ kí o ṣàìgbọràn sí Jèhófà.’ Ǹjẹ́ èyí kọ́ Sọ́ọ̀lù lọ́gbọ́n?

Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù lọ bá àwọn ọmọ Ámálékì jagun, Sámúẹ́lì sì sọ fún un pé kó pa gbogbo wọn pátá. Àmọ́, Sọ́ọ̀lù kò pa Ágágì ọba wọn. Jèhófà wá sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Sọ́ọ̀lù ti fi mí sílẹ̀, kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu mọ́.’ Inú Sámúẹ́lì bà jẹ́ gan-an, ó sì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: ‘Torí pé o kò gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu mọ́, Jèhófà máa fi ẹlòmíì jẹ ọba dípò rẹ.’ Bí Sámúẹ́lì ṣe yí pa dà láti máa lọ, ni Sọ́ọ̀lù bá dì í mú, aṣọ Sámúẹ́lì sì  fàya sí méjì. Sámúẹ́lì wá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: ‘Jèhófà ti fa ìjọba rẹ ya kúrò lọ́wọ́ rẹ.’ Jèhófà máa gbé ìjọba náà fún ẹlòmíì, ó sì máa jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó sì ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

“Ṣíṣègbọràn sàn ju ẹbọ.”​—1 Sámúẹ́lì 15:22