Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 7

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 7

Apá yìí dá lórí ìtàn Ọba Sọ́ọ̀lù àti Ọba Dáfídì. Ìtàn náà sì gba nǹkan bí ọgọ́rin [80] ọdún. Ní ìbẹ̀rẹ̀, Sọ́ọ̀lù kì í gbéra ga, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run, àmọ́ nígbà tó yá, ó yí pa dà, kò sì tẹ̀ lé òfin Jèhófà mọ́. Torí náà, Jèhófà kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Jèhófà sì sọ fún Sámúẹ́lì pé kó yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba tó máa jẹ lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì, ó sì wá ọ̀nà láti pa á, àmọ́ Dáfídì kò gbẹ̀san. Ọmọ Sọ́ọ̀lù tó ń jẹ́ Jónátánì mọ̀ pé Dáfídì ni Jèhófà fẹ́ kó jọba, torí náà ó dúró ti Dáfídì. Nígbà tó yá, Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára, àmọ́ ó gba ìbáwí Jèhófà. Tí o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ rẹ rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé ìṣètò Jèhófà nígbà gbogbo.

NÍ APÁ YÌÍ

Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn onídàájọ́, àmọ́ wọ́n béèrè fún ọba. Sámúẹ́lì yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba àkọ́kọ́, àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba. Kí nìdí?

Dafidi ati Golayati

Jèhófà yan Dáfídì láti jẹ oba tó kàn ní Ísírẹ́lì, ìwà Dáfídì fi hàn pé ọba tọ́ sí i.

Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù

Kí nìdí tí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin yìí fi kórìíra ìkejì, báwo ni ìkejì yìí ṣe hùwà sí èyí tó kórìíra rẹ̀?

Jónátánì Láyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini

Jónátánì tó jẹ́ ọmọ ọba di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Dáfídì.

Ọba Dáfídì Dá Ẹ̀ṣẹ̀

Àṣìṣe kan tó fa ọ̀pọ̀ wàhálà.