Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 33

Rúùtù àti Náómì

Rúùtù àti Náómì

Nígbà kan tí kò sí oúnjẹ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ọmọ Ísírẹ́lì kan tó n jẹ́ Náómì kó lọ sí ilẹ̀ Móábù, òun àti ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì ni wọ́n jọ lọ. Nígbà tó yá, ọkọ Náómì kú. Àwọn ọmọ rẹ̀ sì fẹ́ Rúùtù àti Ópà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Móábù. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ Náómì méjèèjì náà kú.

Nígbà tí Náómì gbọ́ pé oúnjẹ ti wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ó pinnu láti pa dà sílé. Rúùtù àti Ópà sì tẹ̀ lé e, àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ, Náómì sọ fún wọn pé: ‘Ìyàwó dáadáa lẹ jẹ́ fún àwọn ọmọ mi, ẹ sì ṣe dáadáa sí èmi náà. Mo fẹ́ kí ẹ fẹ́ ọkọ míì. Torí náà, ẹ pa dà sí Móábù.’ Àwọn obìnrin náà sọ pé: ‘Màmá, a fẹ́ràn yín gan-an! A kò fẹ́ fi yín sílẹ̀.’ Àmọ́, Náómì ń sọ fún wọn ṣáá pé kí wọ́n pa dà. Nígbà tó yá Ópà pa dà, ó sì ku Rúùtù nìkan. Náómì wá sọ fún un pé: ‘Ópà ti ń pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ àti ọlọ́run rẹ̀. Máa tẹ̀ lé e lọ.’ Àmọ́ Rúùtù sọ pé: ‘Mi ò ní pa dà lẹ́yìn yín. Àwọn èèyàn yín á di èèyàn mi, Ọlọ́run yín á sì di Ọlọ́run mi.’ Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Náómì nígbà tí Rúùtù sọ̀rọ̀ yìí?

Àkókò tí wọ́n ń kórè ọkà báálì ni Rúùtù àti Náómì dé Ísírẹ́lì. Lọ́jọ́ kan, Rúùtù lọ sí oko ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bóásì ọmọ Ráhábù, kó lè lọ kó àwọn ọkà tó jábọ́ nígbà tí wọ́n ń kórè. Bóásì gbọ́ pé ọmọ ilẹ̀ Móábù ni Rúùtù àti pé fúnra rẹ̀ ló pinnu láti dúró ti ìyá ọkọ rẹ̀. Ó wá sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣẹ́ ọkà kù fún Rúùtù kó lè rí kó lọ sílé.

 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Náómì bi Rúùtù pé: ‘Inú oko ta lo ti ṣiṣẹ́ lónìí?’ Rúùtù sọ pé: ‘Oko ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Bóásì ni.’ Náómì wá sọ fún un pé: ‘Ìbátan ọkọ mi ni Bóásì. Máa ṣiṣẹ́ ni oko rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń bá a ṣiṣẹ́. Kò sí nǹkan tó máa ṣe ẹ́.’

Oko Bóásì ni Rúùtù ti ṣiṣẹ́ títí tí àkókò ìkórè náà fi kọ já. Bóásì kíyè sí i pé Rúùtù ṣiṣẹ́ kára, ó sì ní ìwà tó dára. Ní àkókò yẹn, bí ọkùnrin kan bá kú, tí kò sì ní ọmọkùnrin, ìbátan rẹ̀ ló máa fẹ́ ìyàwó tó fi sílẹ̀. Torí náà, Bóásì fẹ́ Rúùtù. Wọ́n sì bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n sọ ní Óbédì. Óbédì ló wá di bàbá bàbá Ọba Dáfídì. Inú àwọn ọ̀rẹ́ Náómì dùn. Wọ́n sọ pé: ‘Jèhófà kọ́kọ́ fún ẹ ní Rúùtù, tó ń tọ́jú rẹ, ní báyìí, ó ti fún ẹ ní ọmọ-ọmọ. A yin Jèhófà lógo.’

“Ọ̀rẹ́ kan wà tí ń fà mọ́ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.”​—Òwe 18:24

Mọ Púpọ̀ Sí I

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

Rúùtù—“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

Kí nìdí tí ìgbéyàwó Rúùtù àti Bóásì fi ṣe pàtàkì? Ẹ̀kọ́ wo ni Rúùtù àti Náómì kọ́ wa nípa ìdílé?

ÀWỌN ÀWÒRÁN ÌTÀN BÍBÉLÌ

Ọ̀rẹ́ Adúróṣinṣin Ni Rúùtù

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Rúùtù kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, ìdúróṣinṣin rẹ̀ mú kó lè jèrè ojú rere Ọlọ́run kó sí rí ìbùkún tó pọ̀ gbà.

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

Rúùtù—“Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ”

Kí nìdí tí Rúùtù fi gbà láti fi ìdílé rẹ̀ àti ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀? Àwọn ànímọ́ wo ni Rúùtù ní tí Jèhófà fi kà á sí ẹni tó ṣeyebíye?

KÁÀDÌ ERÉ BÍBÉLÌ

Káàdì Eré Bíbélì Nípa Rúùtù

Kí nìdí tí Rúùtù fi múra tán láti kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀? Tẹ káàdì eré Bíbélì yìí kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.

KÁÀDÌ ERÉ BÍBÉLÌ

Káàdì Bíbélì Náómì

Náómì ní kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa pe òun ní orúkọ míì.

ERÉ ALÁWÒRÁN

Ọ̀rẹ́ Náómì Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin

Eré aláwòrán yìí á jẹ́ kí àwọn ọmọ ọdún 3 ati 6 kọ́ nípa Rúùtù àti Náómì.

ERÉ ALÁWÒRÁN

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àwọn Ànímọ́ Rúùtù

Eré aláwòrán yìí á jẹ́ kí àwọn ọmọ ọdún 6 sí 8 lè kọ́ bí wọ́n ṣe máa jẹ́ ọ̀rẹ́ rere.

ERÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ FÚN ÀWỌN ỌMỌDÉ

Àwọn Ànímọ́ Tó Yẹ Kí Ọ̀rẹ́ Rere Ní

Eré aláwòrán yìí máa jẹ́ kí àwọn ọmọ ọdún 8 àti 12 lè ní àwọn ànímọ́ tó yẹ kí ọ̀rẹ́ rere ní.