Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 37

Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀

Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀

Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ní àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú àgọ́ ìjọsìn. Hófínì àti Fíníhásì ni orúkọ wọn. Wọn kò pa òfin Jèhófà mọ́ rárá, wọ́n sì ń hùwà tí kò dára sí àwọn èèyàn. Tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú ẹbọ wá fún Jèhófà, Hófínì àti Fíníhásì máa mú èyí tó dára jù lára ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ. Élì gbọ́ nípa ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe, àmọ́ kò ṣe nǹkan kan sí i. Ṣé Jèhófà máa gbà kí irú ìwà yìí máa bá a nìṣó?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì kò dàgbà tó Hófínì àti Fíníhásì, síbẹ̀ kò hùwà búburú ní tirẹ̀. Inú Jèhófà sì ń dùn sí Sámúẹ́lì. Lálẹ́ ọjọ́ kan nígbà tí Sámúẹ́lì ń sùn, ó gbọ́ ohùn kan tó pe orúkọ rẹ̀. Ó sáré dìde lọ bá Élì, ó sì sọ pé: ‘Èmi nìyí!’ Àmọ́ Élì sọ pé: ‘Mi ò pè ẹ́. Pa dà lọ sùn.’ Sámúẹ́lì bá pa dà lọ sùn. Èyí tún ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì. Nígbà tí Sámúẹ́lì gbọ́ ohùn náà nígbà kẹta, Élì wá rí i pé Jèhófà ló ń pe Sámúẹ́lì. Ó sì sọ fún un pé tó bá tún gbọ́ ohùn náà, kí ó sọ pé: ‘Jèhófà, sọ̀rọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’

Sámúẹ́lì pa dà lọ sùn. Lẹ́yìn náà, ohùn náà tún pè é: ‘Sámúẹ́lì! Sámúẹ́lì!’ Ó wá dáhùn pé: ‘Sọ̀rọ̀, nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ ń fetí sílẹ̀.’ Jèhófà  sọ fún un pé: ‘Sọ fún Élì pé, mo máa fi ìyà jẹ òun àti ìdílé rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ọmọ òun ń hùwà tí ò dára nínú àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ kò ṣe nǹkan kan sí i.’ Nígbà ti ilẹ̀ mọ́, Sámúẹ́lì ṣí ilẹ̀kùn àgọ́ ìjọsìn bó ti máa ń ṣe. Ẹ̀rù ń bà á láti jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an sí Élì àlùfáà àgbà. Àmọ́, Élì ránṣẹ́ sí i, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Ọmọ mi, kí ni Jèhófà sọ fún ẹ? Sọ gbogbo ẹ̀ fún mi.’ Ni Sámúẹ́lì bá jíṣẹ́ fún Élì.

Bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà, Jèhófà kò fi í sílẹ̀. Ní gbogbo ilẹ̀ náà ni àwọn èèyàn ti mọ̀ pé Jèhófà ti yan Sámúẹ́lì láti jẹ́ àlùfáà àti adájọ́.

“Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”​—Oníwàásù 12:1