Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n ti máa ń jọ́sìn Jèhófà. Àwọn àlùfáà máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run, àwọn onídàájọ́ sì máa ń darí wọn. Apá yìí máa jẹ́ ká rí i pé ohun tí ẹnì kan bá ṣe lè ṣe àkóbá fún àwọn míì tàbí kó ṣe wọ́n láǹfààní. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. Kọ́ ọmọ rẹ nípa Dèbórà, Náómì, Jóṣúà, Hánà, ọmọ Jẹ́fútà àti Sámúẹ́lì. Jẹ́ kó rí i pé àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe nípa lórí àwọn míì. Tẹnu mọ́ ọn pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì pàápàá irú bíi Ráhábù, Rúùtù, Jáẹ́lì àti àwọn ará Gíbéónì pinnu láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí wọ́n rí i pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.