Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 18

Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan

Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan

Ogójì [40] ọdún ni Mósè fi gbé ní ìlú Mídíánì. Ó fẹ́ ìyàwó, ó sì ní àwọn ọmọ. Lọ́jọ́ kan tó ń tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ̀ nítòsí Òkè Sínáì, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yà á lẹ́nu. Ṣàdédé ló rí i tí iná ń jó igi kékeré kan tó ní ẹ̀gún lára, síbẹ̀ igi náà kò jóná! Nígbà tí Mósè sún mọ́ ìtòsí ibẹ̀ láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó gbọ́ ohùn kan ní àárín igi náà, ohùn yẹn sọ pé: ‘Mósè! Dúró síbi tí o dé yẹn. Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ torí pé ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o wà.’ Jèhófà ló rán áńgẹ́lì kan láti bá Mósè sọ̀rọ̀.

Ẹ̀rù ba Mósè, ó sì bo ojú rẹ̀. Ohùn náà wá sọ pé: ‘Mo ti rí ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, mo sì máa mú wọn lọ sí ilẹ̀ tó dára gan-an. Ìwọ lo sì máa kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’ Ọ̀rọ̀ yẹn máa ya Mósè lẹ́nu gan-an o, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Mósè béèrè pé: ‘Kí ni mo máa sọ tí àwọn èèyàn náà bá béèrè pé ta ló rán mi?’ Ọlọ́run dáhùn pé: ‘Sọ fún wọn pé Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù ló rán mi sí yín.’ Mósè wá sọ pé: ‘Bí àwọn èèyàn náà kò bá fetí sí mi ńkọ́?’ Jèhófà wá ṣe ohun kan táá jẹ́ kó mọ̀ pé òun máa ràn án lọ́wọ́. Ó ní kí Mósè sọ ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Ṣe ni ọ̀pá yẹn di ejò! Nígbà tí Mósè di ìrù ejò náà mú, ó tún pa dà di ọ̀pá. Jèhófà wá sọ pé: ‘Tí wọ́n bá rí ohun tí o ṣe yìí, wọ́n á gbà pé èmi ni mo rán ẹ.’

Mósè wá sọ pé: ‘Àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ.’ Jèhófà ṣe ìlérí fún un pé: ‘Mo máa jẹ́ kí o mọ ohun tí wàá sọ, mo sì máa ní kí Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́.’ Ọkàn Mósè wá balẹ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun, torí náà òun, ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ pa dà sí ìlú Íjíbítì.

“Ẹ má ṣàníyàn nípa báwo tàbí kí ni ẹ ó sọ; nítorí a ó fi ohun tí ẹ ó sọ fún yín ní wákàtí yẹn.”​​—Mátíù 10:19