Nínú àwọn ọmọkùnrin méjìlá [12] tí Jékọ́bù bí, Jósẹ́fù ló jẹ́ ìkọkànlá [11]. Àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù rí i pé òun ni bàbá wọn fẹ́ràn jù. Ǹjẹ́ o mọ bí ó ṣe rí lára wọn? Ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Jósẹ́fù, wọ́n sì kórìíra rẹ̀. Nígbà kan, Jósẹ́fù lá àwọn àlá kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nígbà tó sọ àwọn àlá náà fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, inú wọn kò dùn, wọ́n rò pé ṣe ló ń dọ́gbọ́n sọ pé àwọn máa tẹrí ba fún un lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn wá mú kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù kó àwọn àgùntàn wọn lọ jẹ oko nítòsí ìlú Ṣékémù. Jékọ́bù wá rán Jósẹ́fù pé kó lọ wò wọ́n láti mọ̀ bóyá àlàáfíà ni wọ́n wà. Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù rí i lọ́ọ̀ọ́kán, wọ́n sọ fún ara wọn pé: ‘Ọmọ tó máa ń lá àlá yẹn ló ń bọ̀ yẹn. Ẹ jẹ́ ká pa á!’ Wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò jíjìn. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń jẹ́ Júdà sọ pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ ká pa á! Ẹ jẹ́ ká tà á gẹ́gẹ́ bí ẹrú.’ Torí náà, wọ́n ta Jósẹ́fù ní ogún [20] owó fàdákà fún àwọn oníṣòwò Mídíánì tó ń lọ sí Íjíbítì.

Lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù mú aṣọ rẹ̀, wọ́n kì í sínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́, wọ́n wá fi aṣọ náà ránṣẹ́ sí bàbá wọn, wọ́n sì sọ fún un pé: ‘Wo aṣọ yìí, ṣé kì í ṣe aṣọ Jósẹ́fù?’ Nígbà tí Jékọ́bù rí i, inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Ó rò pé ẹranko kan ló pa Jósẹ́fù jẹ. Inú rẹ̀ bà jẹ́ débi pé kò sẹ́ni tó lè tù ú nínú.

Nígbà tí àwọn oníṣòwò yẹn dé Íjíbítì, wọ́n ta Jósẹ́fù lẹ́rú fún olóyè kan tó ń jẹ́ Pọ́tífárì. Àmọ́, Jèhófà kò fi Jósẹ́fù sílẹ̀. Pọ́tífárì kíyè sí i pé Jósẹ́fù kì í fi iṣẹ́ ṣeré àti pé ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Bí Pọ́tífárì ṣe ní kó máa bójú tó gbogbo ilé òun nìyẹn.

 Ìyàwó Pọ́tífárì kíyè sí i pé Jósẹ́fù jẹ́ ọkùnrin tó rẹwà, àti pé ó lágbára. Ojoojúmọ́ ló máa ń sọ fún Jósẹ́fù pé kí ó wá bá òun sùn. Kí ni Jósẹ́fù wá ṣe? Jósẹ́fù kò gbà, ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Rárá o! Mi ò ṣe. Ọkọ yín gbẹ́kẹ̀ lé mi, ẹ̀yin sì ni ìyàwó rẹ̀. Tí mo bá sùn tì yín, ẹ̀ṣẹ̀ ni lójú Ọlọ́run.’

Lọ́jọ́ kan, ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ fi dandan mú Jósẹ́fù kó lè bá a sùn. Ó di aṣọ Jósẹ́fù mú, àmọ́ Jósẹ́fù sá jáde. Nígbà tí Pọ́tífárì pa dà dé, obìnrin náà parọ́ mọ́ Jósẹ́fù, ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé Jósẹ́fù fẹ́ fi ipá bá òun sùn. Inú bí Pọ́tífárì gan-an, ó sì ní kí wọ́n ju Jósẹ́fù sí ẹ̀wọ̀n. Síbẹ̀, Jèhófà kò gbàgbé Jósẹ́fù.

“Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.”​—1 Pétérù 5:6