Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 21

Ìyọnu Kẹwàá

Ìyọnu Kẹwàá

Mósè ṣèlérí fún Fáráò pé òun ò ní wá sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. Àmọ́ kí Mósè tó lọ, ó sọ fún Fáráò pé: ‘Tó bá di òru, gbogbo àkọ́bí ẹ̀yin ará Íjíbítì máa kú, láti orí ọmọkùnrin Fáráò títí dé ọmọ àwọn ẹrú.’

Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n se oúnjẹ pàtàkì kan. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ pa àgbò kan tàbí òbúkọ kan tó ti pé ọdún kan, kí ẹ sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sàmì síbi ìlẹ̀kùn ilé yín. Kí ẹ wá sun ẹran náà, kí ẹ sì fi búrẹ́dì aláìwú jẹ ẹ́. Kí ẹ wọ aṣọ àti bàtà yín, kí ẹ sì múra tán láti kúrò ní Íjíbítì. Òru yìí ni màá dá yín nídè.’ Báwo lo ṣe rò pé á rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ṣé inú wọn máa dùn àbí kò ní dùn?

Nígbà tó di òru, áńgẹ́lì Jèhófà lọ sí gbogbo ilé tó wà ní Íjíbítì. Tí ó bá ti dé ilé tí wọn kò fi ẹ̀jẹ̀ sàmì síbi ìlẹ̀kùn, àkọ́bí wọn máa kú. Àmọ́ ó máa ré kọjá àwọn ilé tí wọ́n bá fi ẹ̀jẹ̀ sàmì sí. Gbogbo àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì ló kú àti ọmọ olówó àti ọmọ tálákà. Àmọ́ kò sí ọmọ Ísírẹ́lì kankan tí ó kú.

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọmọ Fáráò náà kú? Ìyẹn ló fà á tí ara Fáráò kò fi lè gbà á mọ́. Ló bá ránṣẹ́ pe Mósè àti Áárónì ní kíá, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ó yá, ó yá. Ẹ jáde kúrò ní ìlú wa. Ẹ lọ máa jọ́sìn Ọlọ́run yín. Ẹ kó gbogbo ẹran yín, kí ẹ máa lọ!’

Àárín òru tí òṣùpá mọ́lẹ̀ rokoṣo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì,  wọ́n ṣètò ara wọn ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, àti ní ẹbí kọ̀ọ̀kan. Iye àwọn ọkùnrin tí ó wà láàárín wọn jẹ́ 600,000. Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé tó pọ̀ gan-an sì tún wà pẹ̀lú wọn. Àwọn míì tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì náà bá wọn lọ kí wọ́n lè jọ máa sin Jèhófà. Níkẹyìn, Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú!

Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa rántí bí òun ṣe dá wọn nídè, torí náà ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ pàtàkì yẹn lọ́dọọdún. Èyí ni wọ́n ń pè ní Ìrékọjá.

“Fún ìdí yìí gan-an ni mo ṣe jẹ́ kí o máa wà nìṣó, pé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí èmi lè fi agbára mi hàn, àti pé kí a lè polongo orúkọ mi ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”​—Róòmù 9:17