Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 15

Jèhófà Kò Gbàgbé Jósẹ́fù

Jèhófà Kò Gbàgbé Jósẹ́fù

Ohun kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan nígbà tí Jósẹ́fù wà ní ẹ̀wọ̀n. Fáráò tó jẹ́ ọba Íjíbítì lá àlá kan, kò sì sí ẹni tó lè túmọ̀ àlá náà fún un. Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Fáráò wá sọ fún un pé Jósẹ́fù lè túmọ̀ àlá náà. Bí Fáráò ṣe ní kí wọ́n lọ pe Jósẹ́fù wá nìyẹn.

Fáráò bi Jósẹ́fù pé: ‘Ṣé o lè sọ ohun tí àlá mi túmọ̀ sí?’ Jósẹ́fù sọ fún Fáráò pé: ‘Ọdún méje gbáko ni ọ̀pọ̀ oúnjẹ fi máa wà ní Íjíbítì, lẹ́yìn náà, kò ní sí oúnjẹ fún odindi ọdún méje. Torí náà, yan ẹnì kan tó gbọ́n dáadáa pé kó máa kó oúnjẹ pa mọ́ kí ebi má bàa pa àwọn èèyàn nígbà tí kò bá sí oúnjẹ.’ Fáráò wá dáhùn pé: ‘Ìwọ gan-an ni mo yàn! Mo máa fi ẹ́ ṣe igbá-kejì mi nílẹ̀ Íjíbítì!’ Báwo ni Jósẹ́fù ṣe mọ ohun tí àlá Fáráò túmọ̀ sí? Jèhófà ló jẹ́ kó mọ̀ ọ́n.

Ní gbogbo ọdún méje tó tẹ̀ lé e, ṣe ni Jósẹ́fù ń kó oúnjẹ pa mọ́. Nígbà tó yá, kò sí oúnjẹ ní gbogbo ayé, gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti sọ. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wá láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Jósẹ́fù. Nígbà tí Jékọ́bù bàbá rẹ̀ gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Íjíbítì, ó rán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́wàá pé kí wọ́n lọ ra oúnjẹ wá.

Nígbà tí àwọn ọmọ Jékọ́bù dé ọ̀dọ̀ Jósẹ́fù, kíá ni Jósẹ́fù ti dá wọn mọ̀. Àmọ́, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kò mọ̀ pé Jósẹ́fù ni. Ṣé o rántí pé Jósẹ́fù lá àlá pé wọ́n máa tẹrí ba fún òun? Ohun tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì ṣe gan-an nìyẹn. Jósẹ́fù fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣì kórìíra ara wọn. Torí náà, ó sọ fún wọn pé: ‘Amí ni yín. Ńṣe ni ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa bá orílẹ̀-èdè wa jà.’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Kò rí bẹ́ẹ̀! Àwa méjìlá [12] ni bàbá wá bí, ilẹ̀ Kénáánì la  sì ń gbé. Àbúrò wa kan ti kú, èyí àbígbẹ̀yìn sì wà pẹ̀lú bàbá wa.’ Jósẹ́fù wá sọ fún wọn pe: ‘Ẹ mú àbígbẹ̀yìn náà wá tí ẹ bá ń pa dà bọ̀, kí n lè mọ̀ pé òtítọ́ lẹ̀ ń sọ.’ Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sílé lọ́dọ̀ bàbá wọn.

Nígbà tí oúnjẹ tán nílé, Jékọ́bù tún rán àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí Íjíbítì. Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n mú Bẹ́ńjámínì tó jẹ́ àbígbẹ̀yìn bàbá wọn dání. Jósẹ́fù ṣe ohun kan láti dán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wò, ó fi kọ́ọ̀pù rẹ̀ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sínú báàgì tí Bẹ́ńjámínì kó oúnjẹ sí, ó wá sọ pé ṣe ni wọ́n jí kọ́ọ̀pù náà. Ó ya àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù lẹ́nu gan-an nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Jósẹ́fù bá kọ́ọ̀pù náà nínú báàgì Bẹ́ńjámínì. Wọ́n bẹ Jósẹ́fù pé kó fìyà jẹ àwọn dípò Bẹ́ńjámínì.

Jósẹ́fù wá rí i pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti yíwà pa dà lóòótọ́. Jósẹ́fù kò lè mú ọ̀rọ̀ náà mọ́ra mọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣe? Ó bú sẹ́kún, ó wá sọ pé: ‘Èmi ni Jósẹ́fù àbúrò yín. Ṣé bàbá mi ṣì wà láyé?’ Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ lẹ́nu. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má ba inú jẹ́ torí ohun tí ẹ ṣe sí mi. Ọlọ́run ló rán mi wá síbí kí n lè gba ẹ̀mí yín là. Ó yá, ẹ tètè lọ mú bàbá mi wá síbí.’

Wọ́n pa dà sílé, wọ́n sọ fún bàbá wọn pé Jósẹ́fù ṣì wà láàyè, àwọn àti bàbá wọn sì lọ sí Íjíbítì. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Jósẹ́fù àti bàbá rẹ̀ tún pa dà rí ara wọn.

“Bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.” ​​—Mátíù 6:15