Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 4

Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀

Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀

Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Kéènì lorúkọ ọmọ tí wọ́n kọ́kọ́ bí, iṣẹ́ àgbẹ̀ ló ń ṣe. Ébẹ́lì lọmọ wọn kejì, àwọn àgùntàn ni òun máa ń bójú tó ní tiẹ̀.

Lọ́jọ́ kan, àwọn méjèèjì rú ẹbọ sí Jèhófà. Ṣé o mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí? Ńṣe ni wọ́n fún Jèhófà ní ẹ̀bùn pàtàkì. Inú Jèhófà dùn sí ẹbọ Ébẹ́lì, àmọ́ inú rẹ̀ kò dùn sí ẹbọ Kéènì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bí Kéènì nínú gan-an. Jèhófà wá kìlọ̀ fún Kéènì pé inú tó ń bí i lè mú kó ṣe nǹkan tó burú. Àmọ́, Kéènì kò gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Kéènì ṣe? Ó sọ fún Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ pé: ‘Jẹ́ ká jọ lọ sí oko.’ Nígbà tí wọ́n dé inú oko, Kéènì fi  nǹkan lu àbúrò rẹ̀, ó sì pa á. Kí lo rò pé Jèhófà máa ṣe? Jèhófà fìyà jẹ Kéènì, ó lé e kúrò nílé pátápátá. Kéènì kò lè pa dà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀ mọ́.

Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ ẹ? O lè máa bínú bí nǹkan kò bá rí bí o ṣe fẹ́. Bóyá o máa ń bínú gan-an débi pé àwọn èèyàn ti ń kìlọ̀ fún ẹ. Á dáa kí o tètè wá nǹkan ṣe, kí o sì yí ìwà pa dà. Ìdí ni pé tí o kò bá tètè wá nǹkan ṣe, ìbínú lè mú kí o hùwà burúkú.

Ébẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì níwà tó dáa, ìdí nìyẹn tí Jèhófà kò fi gbàgbé rẹ̀ láé. Jèhófà máa jí Ébẹ́lì dìde nígbà tí ayé bá di Párádísè.

“Kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”​​—Mátíù 5:24