Ọ̀dọ́kùnrin kan wà ní ìjọ Lísírà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tímótì. Gíríìkì ni bàbá rẹ̀, màmá rẹ̀ sì jẹ́ Júù. Láti kékeré ni màmá rẹ̀ tó ń jẹ́ Yùníìsì àti màmá rẹ̀ àgbà tó ń jẹ́ Lọ́ìsì tí kọ́ ọ nípa Jèhófà.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń rin ìrìn àjò ìkejì láti lọ wàásù, ó lọ sí ìjọ Lísírà. Ó wá kíyè sí i pé Tímótì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, ó sì máa ń fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù wá ní kí Tímótì tẹ̀ lé òun kí àwọn lè jọ máa rin ìrìn àjò. Pọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Tímótì bó ṣe máa wàásù ìhìn rere àti bó ṣe máa kọ́ àwọn èèyàn.

Ẹ̀mí mímọ́ ló máa ń darí Pọ́ọ̀lù àti Tímótì sí ibi tí wọ́n máa lọ. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan. Nínú ìran yẹn, ọkùnrin kan sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó wá sí Makedóníà láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí náà, Pọ́ọ̀lù, Tímótì, Sílà àti Lúùkù lọ sí Makedóníà láti lọ wàásù, wọ́n sì dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀.

Ìlú kan wà ní àgbègbè Makedóníà tó ń jẹ́ Tẹsalóníkà, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló di Kristẹni níbẹ̀. Àmọ́ àwọn Júù kan bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Pọ́ọ̀lù àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ni wọ́n bá kó èrò rẹpẹtẹ, wọ́n sì mú àwọn Kristẹni kan lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ, wọ́n wá ń pariwo pé: ‘Ọ̀tá ni àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ fún ìjọba Róòmù!’ Ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù àti Tímótì wà nínú ewu, nígbà tó di alẹ́, ńṣe ni wọ́n sá lọ sí ìlú Bèróà.

Inú àwọn tó wà ní ìlú Bèróà dùn gan-an láti gbọ́ ìhìn rere, torí náà ọ̀pọ̀ àwọn Júù àti Gíríìkì ló di Kristẹni. Àmọ́ àwọn Júù kan tún wá láti ìlú Tẹsalóníkà kí wọ́n lè dá wàhálà sílẹ̀, torí náà Pọ́ọ̀lù kúrò ní Bèróà, ó sì lọ sí Áténì. Tímótì àti Sílà ní tiwọn dúró ní Bèróà kí wọ́n lè ran àwọn ará lọ́wọ́. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì pa dà sí ìlú Tẹsalóníkà kó lè ran àwọn ará lọ́wọ́ torí pé àwọn èèyàn  ń takò wọ́n gan-an. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù rán Tímótì lọ sí ọ̀pọ̀ ìjọ kó lè lọ ran àwọn ará lọ́wọ́.

Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: ‘Àwọn èèyàn máa tako àwọn tó bá fẹ́ jọ́sìn Jèhófà.’ Wọ́n sì tako Tímótì, kódà wọ́n jù ú sí ẹ̀wọ̀n torí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Àmọ́ inú rẹ̀ dùn pé òun ní àǹfààní láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.

Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará ní ìlú Fílípì pé: ‘Mo máa rán Tímótì sí yín. Ó máa kọ́ yín nípa bí ẹ ṣe lè jẹ́ olóòótọ́, á sì kọ́ yín ní bí ẹ ṣe máa wàásù.’ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tí òun bá fún Tímótì ní iṣẹ́ ńlá, ó máa ṣe é. Torí náà, wọ́n jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

“Èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín. Nítorí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Kristi Jésù.” ​—Fílípì 2:​20, 21