Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 102

Ìran Tí Jòhánù Rí

Ìran Tí Jòhánù Rí

Wọ́n fi àpọ́sítélì Jòhánù sí ẹ̀wọ̀n ní ìlú Pátímọ́sì. Ibẹ̀ ló wà nígbà tí Jésù fi ìran mẹ́rìndínlógún [16] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ hàn án. Ìran ni àwòrán àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Nínú àwọn ìran yìí, Jòhánù rí bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́, bí Ìjọba rẹ̀ ṣe máa dé àti bí ayé ṣe máa rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.

Nínú ìran kan, Jòhánù rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] sì jókòó yíká ìtẹ́ náà. Àwọn alàgbà náà wọ aṣọ funfun, adé wúrà sí wà lórí wọn. Bí àrá ṣe ń sán, bẹ́ẹ̀ ni iná ń tàn yòò láti ibi ìtẹ́ náà. Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] yìí tẹrí ba fún Jèhófà, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. Nínú ìran míì, Jòhánù rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó wá láti oríṣiríṣi ìlú, tí wọ́n sì ń sọ oríṣiríṣi èdè tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà. Jésù tó jẹ́ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà sì ń darí wọn lọ sí ibi tí omi ìyè wà. Nígbà tó yá, Jòhánù rí ìran míì níbi tí Jésù àti àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún [24] ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ọ̀run. Nínú ìran tó tẹ̀ lé e, Jòhánù rí i tí Jésù bá Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ jagun. Jésù ṣẹ́gun, ó sì lé wọn kúrò ní ọ̀run wá sí ayé.

 Jòhánù tún rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti àwọn 144,000 tí wọ́n dúró lórí Òkè Síónì. Ó tún rí áńgẹ́lì kan tó ń fò nítòsí ayé, tó ń sọ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n sì fi ògo fún un.

Nínú ìran tó tẹ̀ lé e, Jòhánù rí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Nínú ogun yẹn, Jésù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣẹ́gun Sátánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Nínú ìran tó kẹ́yìn, Jòhánù rí bí àwọn tó wà ní ọ̀run àti àwọn tó wà ní ayé ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Sátánì àti gbogbo àwọn tó ń ṣe ibi sì pa run. Gbogbo àwọn tó wà ní ọ̀run àti àwọn tó wà ní ayé wá ń yin orúkọ Jèhófà, wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀.

“I will put enmity between you and the woman and between your offspring and her offspring. He will crush your head, and you will strike him in the heel.”​—Genesis 3:15