Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 14

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 14

Àwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn ibi tó jìnnà jù láyé. Jésù ló pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wàásù, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu tó jẹ́ kí wọ́n lè máa fi oríṣiríṣi èdè kọ́ àwọn èèyàn. Jèhófà tún fún wọn ní ìgboyà, ó sì fún wọn ní agbára kí wọ́n lè borí àtakò tó le.

Jésù fi ìran kan han àpọ́sítélì Jòhánù, ó sì jẹ́ kó rí ògo Jèhófà. Nínú ìran míì, Jòhánù rí bí Jésù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ṣe ṣẹ́gun Sátánì, tí wọn kò sì jé kó máa ṣiṣẹ́ ibi mọ́ títí láé. Jòhánù rí i tí Jésù di Ọba, ó sì rí àwọn 144,000 tó ń jọba pẹ̀lú rẹ̀. Jòhánù tún rí bí gbogbo ayé ṣe di Párádísè, tí gbogbo èèyàn wà ní àlàáfíà, tí wọ́n sì ń jọ́sìn Jèhófà ní ìṣọ̀kan.

NÍ APÁ YÌÍ

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Nǹkan ìyanu wo ni ẹ̀mí mímọ́ mú kí wọ́n ṣe?

Kò Sí Ohun Tó Lè Dá Wọn Dúró

Àwọn aṣáájú ìsìn tó pa Jésù ń wá bí wọ́n á ṣe dá iṣẹ́ ìwàásù àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dúró. Àmọ́ wọn ò rí i ṣe.

Jésù Yan Sọ́ọ̀lù

Ọ̀tá àwọn Kristẹni ni Sọ́ọ̀lù, àmọ́ nǹkan máa tó yí pa dà.

Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rán Pétérù lọ sílé ọkùnrin tí kì í ṣe Júù?

Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò mú ìhìn rere lọ sáwọn ìlú tó jìnnà.

Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ẹ máa kà nípa ẹ̀mí èṣù kan, ìmìtìtì ilẹ̀ àti idà kan nínú ìtàn yìí?

Pọ́ọ̀lù àti Tímótì

Àwọn méjèèjì jọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àti arákùnrin fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù

Ewu pọ̀ lójú ọ̀nà, ṣùgbọ́n kò sóhun tó lè dá àpọ́sítélì yìí dúró.

Ìran Tí Jòhánù Rí

Jésù fi àwọn ìran nípa ọjọ́ iwájú hàn án.

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

Jòhánù rí ìran nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe.