Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 85

Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì

Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì

Àwọn Farisí kórìíra Jésù, wọ́n sì ń wá bí wọ́n ṣe máa mú un. Wọ́n sọ pé kò gbọ́dọ̀ wo èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. Ní ọjọ́ Sábáàtì kan, Jésù rí afọ́jú kan tó ń tọrọ owó lójú ọ̀nà. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ máa rí bí agbára Ọlọ́run ṣe máa ran ọkùnrin yìí lọ́wọ́.’ Jésù po itọ́ mọ́ iyẹ̀pẹ̀, ó sì fi sí ojú ọkùnrin náà. Jésù wá sọ fún un pé: ‘Lọ fọ ojú rẹ nínú adágún Sílóámù.’ Ọkùnrin yẹn ṣe bẹ́ẹ̀, bó ṣe ríran fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀ nìyẹn.

Ẹnu ya àwọn èèyàn gan-an. Wọ́n sì ń sọ pé: ‘Ṣé ọkùnrin tó máa ń tọrọ owó nìyí àbí ẹni yìí kàn jọ ọ́ ni?’ Ọkùnrin náà sọ pé: ‘Èmi náà ni.’ Àwọn èèyàn wá bi í pé: ‘Báwo ló ṣe wá ríran?’ Nígbà tó ṣàlàyé fún wọn, wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisí.

Ọkùnrin náà sọ fún àwọn Farisí pé: ‘Jésù fi iyẹ̀pẹ̀ sí ojú mi, ó sì ní kí n lọ fọ̀ ọ́ kúrò. Ohun tí mo ṣe nìyẹn, mo sì ti ríran báyìí.’ Àwọn Farisí wá sọ pé: ‘Tí Jésù bá ń wo èèyàn sàn lọ́jọ́ sábáàtì, á jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni agbára rẹ̀ ti wá.’ Àmọ́, àwọn kan sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ ni agbára rẹ̀ ti wá, kò ní lè wo ẹnì kankan sàn rárá.’

Àwọn Farisí pe àwọn òbí ọkùnrin náà, wọ́n sì bi wọ́n pé: ‘Báwo ni ọmọ yín ṣe ríran?’ Ẹ̀rù ń ba àwọn òbí rẹ̀ torí pé àwọn Farisí ti sọ pé tí ẹnikẹ́ni bá gba Jésù gbọ́, àwọn máa lé ẹni náà kúrò  nínú sínágọ́gù. Torí náà, àwọn òbí rẹ̀ sọ pé: ‘A ò mọ bó ṣe ṣẹlẹ̀. Ẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.’ Àwọn Farisí wá bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bo ọkùnrin náà títí tó fi sọ pé: ‘Mo ti sọ gbogbo ohun tí mo mọ̀ fún yín, kí ló dé tí ẹ tún ń bi mí ní ìbéèrè? Inú bí àwọn Farisí gan-an, bí wọ́n ṣe ju ọkùnrin náà síta nìyẹn.

Jésù lọ wá ọkùnrin yẹn, ó sì bi í pé: ‘Ṣé o ní ìgbàgbọ́ nínú Mèsáyà?’ Ọkùnrin náà sọ pé: ‘Mo máa ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ tí mo bá mọ ẹni tó jẹ́.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Èmi ni Mèsáyà?’ Ẹ ò rí i pé Jésù láàánú àwọn èèyàn gan-an. Kì í ṣe pé Jésù kàn la ojú ọkùnrin yẹn nìkan, ó tún ràn án lọ́wọ́ kó lè ní ìgbàgbọ́.

“Ẹ ṣàṣìṣe, nítorí ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run.”​—Mátíù 22:29