Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 83

Jésù Fún Àwọn Èèyàn Púpọ̀ ní Oúnjẹ

Jésù Fún Àwọn Èèyàn Púpọ̀ ní Oúnjẹ

Àkókò díẹ̀ ṣáájú àjọyọ̀ Ìrékọjá lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni, àwọn àpọ́sítélì pa dà dé láti ibi tí wọ́n ti lọ wàásù. Ó ti rẹ̀ wọ́n, torí náà, àwọn àti Jésù jọ wọ ọkọ̀ ojú omi lọ síbì kan tí wọ́n ti lè sinmi ní Bẹtisáídà. Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá dúró dè wọ́n níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù fẹ́ dá wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, síbẹ̀ ó wá àyè fún àwọn èèyàn náà. Ó wo àwọn tó ń ṣàìsàn láàárín wọn sàn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ ni Jésù fi kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: ‘Ebi á ti máa pa àwọn èèyàn náà, sọ pé kí wọ́n máa lọ kí wọ́n lè lọ ra nǹkan tí wọ́n máa jẹ.’

Jésù sọ pé: ‘Kò di dandan pé kí wọ́n lọ. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ níbí.’ Àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wá bi í pé: ‘Ṣẹ́ o fẹ́ kí a lọ ra oúnjẹ fún wọn ni?’ Ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó ń jẹ́ Fílípì wá sọ fún un pé: ‘Tí a bá tiẹ̀ ní owó rẹpẹtẹ, a ò ní lè ra oúnjẹ fún gbogbo èèyàn yìí.’

Jésù bi wọ́n pé: ‘Báwo ni oúnjẹ tí a ní ṣe pọ̀ tó?’ Áńdérù sọ pé: ‘A ní búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja kékeré méjì, ó sì dájú pé ìyẹn ò lè tó.’ Jésù wá sọ pé: ‘Ẹ kó búrẹ́dì àti ẹja náà wá.’ Ó ní kí àwọn èèyàn náà jókòó sórí koríko ní àwùjọ àádọ́ta [50] àti ọgọ́rùn-ún [100]. Jésù mú búrẹ́dì àti ẹja náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì gbàdúrà. Ó wá gbé oúnjẹ náà fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, àwọn yẹn sì pín in fáwọn èèyàn náà. Àwọn ọkùnrin 5,000 àti àwọn  obìnrin àti àwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ ló jẹun títí wọ́n fi yó. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn àpọ́sítélì náà kó oúnjẹ tó ṣẹ́ kù jọ sínú apẹ̀rẹ̀ kó má bàa ṣòfò. Odindi apẹ̀rẹ̀ méjìlá ló ṣẹ́ kù! Àbí ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìyanu ńlá nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Inú àwọn èèyàn náà dùn débi pé wọ́n fẹ́ fi Jésù jọba. Àmọ́, Jésù mọ̀ pé Jèhófà kò tíì fẹ́ kí òun di ọba. Torí náà, ó ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, ó sì ní kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọdá sí òdì kejì Òkun Gálílì. Nígbà tí wọ́n wọ inú ọkọ̀, Jésù dá lọ sórí òkè. Ǹjẹ́ ẹ mọ ìdí tó fi dá lọ síbẹ̀? Ìdí ni pé ó fẹ́ lọ gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀. Kò sí bí iṣẹ́ Jésù ti pọ̀ tó, ó máa ń wáyè láti gbàdúrà.

“Ẹ ṣiṣẹ́, kì í ṣe fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, bí kò ṣe fún oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọmọ ènìyàn yóò fún yín.” ​—Jòhánù 6:27