Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 74

Jésù Di Mèsáyà

Jésù Di Mèsáyà

Jòhánù ti ń wàásù fún àwọn èèyàn pé: ‘Ẹnì kan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀.’ Nígbà tí Jésù pé ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún, ó wá sí Odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn èèyàn. Jésù fẹ́ kí Jòhánù ṣe ìrìbọmi fún òun, àmọ́ Jòhánù sọ pé: ‘Ìwọ ló yẹ kí o ṣe ìrìbọmi fún mi, kì í ṣe èmi ló yẹ kí n ṣe ìrìbọmi fún ẹ.’ Jésù wá sọ fún Jòhánù pé: ‘Jèhófà fẹ́ kí o ṣe ìrìbọmi fún mi.’ Torí náà, àwọn méjèèjì lọ sínú Odò Jọ́dánì, Jòhánù sì ki Jésù bọ inú omi náà pátápátá.

Lẹ́yìn tí Jésù jáde kúrò nínú omi, ó gbàdúrà sí Jèhófà. Bí Jésù ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó dà bí ẹyẹ àdàbà sì bà lé Jésù. Jèhófà wá sọ̀rọ̀ láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”

Nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bà lé Jésù, Jésù di Kristi tàbí Mèsáyà. Àkókò wá tó báyìí fún Jésù láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí Jèhófà rán an pé kó wá ṣe ní ayé.

Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló lọ sí aginjù, ó sì lo ogójì [40] ọjọ́ níbẹ̀. Nígbà tó kúrò ní aginjù, ó lọ sọ́dọ̀ Jòhánù. Bí Jòhánù ṣe rí Jésù lọ́ọ̀ọ́kán, ó sọ pé: ‘Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run ni ó ń bọ̀ yìí, òun ló máa kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.’ Ohun tí Jòhánù sọ yìí jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́, ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tó wà ní aginjù? Jẹ́ ká wò ó.

“Ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: ‘Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’”​—Máàkù 1:11