Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 12

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 12

Jésù kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó tún kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Tí o bá jẹ́ òbí, ṣàlàyé ohun tí àdúrà yẹn túmọ̀ sí fún ọmọ rẹ. Jésù ò jẹ́ kí Sátánì sọ òun di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run. Nígbà tó yá, Jésù yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, àwọn ni wọ́n sì kọ́kọ́ di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run. Tẹnu mọ́ bí Jésù ṣe ní ìtara fún ìjọsìn tòótọ́. Torí pé Jésù fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ, ó tiẹ̀ tún jí òkú dìde. Àwọn ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo èèyàn.

NÍ APÁ YÌÍ

Jésù Di Mèsáyà

Kí ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó pe Jésù ní Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run?

Èṣù Dán Jésù Wò

Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èṣù dán Jésù wò. Kí làwọn ìdẹwò mẹ́ta náà? Báwo ni Jésù ṣe dáhùn pa dà?

Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì

Kí nìdí tí Jésù fi lé àwọn ẹran tó wà nínú tẹ́ńpìlì tó sì da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù?

Obìnrin kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga

Ẹnu ya obìnrin ará Samáríà kan pé Jésù bá òun sọ̀rọ̀. Kí nìdí? Kí ni Jésù sọ fún un tó jẹ́ pé kò sọ fún ẹlòmí ì rí?

Jésù Wàásù Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Jésù sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wá di “apẹja ènìyàn.” Nígbà tó yá, ó kọ́ àádọ́rin lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa wàásù ìhìn rere náà.

Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu

Gbogbo ibi tó bá lọ làwọn aláìsàn máa ń wá bá a kó lè wò wọ́n sàn. Ó tiẹ̀ jí ọmọbìnrin kan tó ti kú dìde.

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

Kí ló dé tó fi yàn wọ́n? Ǹjẹ́ o rántí orúkọ wọn?

TÌwàásù Lórí Òkè

Jésù kọ́ àwọn èèyàn tó péjọ ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan.

Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà

Àwọn nǹkan wo ni Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa béèrè?

Jésù Fún Àwọn Èèyàn Púpọ̀ ní Oúnjẹ

Kí ni iṣẹ́ ìyanu yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jésù àti Jèhófà?

Jésù Rìn Lórí Omi

Ǹjẹ́ o lè fọkàn yàwòrán bó ṣe máa rí lára àwọn àpọ́sítélì lẹ́yìn tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí?

Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì

Kí nìdí tí inú gbogbo èèyàn ò ṣe dùn sí ohun tí Jésù ṣe?

Jésù Jí Lásárù Dìde

Nígbà tí Jésù rí i tí Màríà ń sunkún, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Àmọ́ ẹkún wọn dayọ̀ lẹ́yìn-ò-rẹyìn.