Jòhánù ọmọ Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì di wòlíì Ọlọ́run nígbà tó dàgbà. Jèhófà lo Jòhánù láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé Mèsáyà ń bọ̀. Àmọ́, dípò kí Jòhánù máa kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù tàbí nínú ìlú, inú aginjù ló ti ń kọ́ wọn. Àwọn èèyàn wá láti Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jòhánù. Ó kọ́ wọn pé tí wọ́n bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, wọ́n gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ohun búburú. Ọ̀rọ̀ tí Jòhánù bá wọn sọ mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn ronú pìwà dà, Jòhánù sì ṣe ìrìbọmi fún wọn nínú Odò Jọ́dánì.

Jòhánù kì í ṣe olówó. Asọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe ló máa ń wọ̀, kòkòrò kan tí wọ́n ń pè ní eéṣú àti oyin ìgàn ló sì máa ń jẹ. Àwọn èèyàn máa ń wò ó pé irú èèyàn wo ni eléyìí. Kódà, àwọn Farisí àti àwọn Sadusí tí wọ́n jẹ́ agbéraga wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Jòhánù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ yí ìwà yín pa dà. Ẹ má rò pé èèyàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni yín torí ẹ sọ pé ọmọ Ábúráhámù ni yín. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọmọ Ọlọ́run ni yín.’

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wá sọ́dọ̀ Jòhánù, wọ́n á sì bi í pé: ‘Kí la máa ṣe kí inú Ọlọ́run lè dùn sí wa?’ Jòhánù máa ń sọ fún wọn pé: ‘Kí ẹni tó ní aṣọ méjì fún ẹni tí kò ní rárá ní aṣọ kan.’ Ṣé o mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó fẹ́ kí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀ pé tí wọ́n bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn míì.

Jòhánù sọ fún àwọn agbowó orí pé: ‘Ẹ má ṣe rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ.’ Ó tún sọ fún àwọn sójà pé: ‘Ẹ má ṣe gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí ẹ sì máa sọ òtítọ́.’

 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì náà wá bá Jòhánù, wọ́n sì bi í pé: ‘Ta ni ẹ́? Torí pé gbogbo èèyàn ló fẹ́ mọ̀ ẹ́.’ Jòhánù wá sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni ohùn ẹni tí ń ké jáde ní aginjù pé, ẹ mú kí ọ̀nà Jèhófà tọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀.’

Inú àwọn èèyàn ń dùn sí ohun tí Jòhánù ń kọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì ń ronú pé òun gan-an ni Mèsáyà. Àmọ́, ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹnì kan ń bọ̀ tí ó tóbi jù mí lọ, okùn bàtà rẹ̀ ni èmi kò sì lè tú. Èmi ń bátisí pẹ̀lú omi, àmọ́ ẹni yẹn yóò bátisí yín pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́.’

“Ọkùnrin yìí wá fún ẹ̀rí, láti lè jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ náà, kí onírúurú ènìyàn gbogbo bàa lè gbà gbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.”​—Jòhánù 1:7