Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 11

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 11

Apá yìí dá lórí ìtàn tó bẹ̀rẹ̀ láti Mátíù dé Ìṣípayá. Inú ìdílé kan tí kò lówó ni wọ́n bí Jésù sí. Inú abúlé kékeré kan sì ni wọ́n ń gbé. Ó bá bàbá rẹ̀ ṣe iṣẹ́ káfíńtà. Jésù lẹ́ni tó máa gba aráyé là. Jèhófà ti yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba ọ̀run. Tí o bá jẹ́ òbí, ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọyì bí Jèhófà ṣe fara balẹ̀ yan irú ìdílé àti àyíká tí Jésù máa dàgbà sí. Tún ṣàyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Jésù lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù tó fẹ́ pa á àti bí kò ṣe sí ohunkóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe yan Jòhánù láti múra ọ̀nà sílẹ̀ fún Jésù. Tẹnu mọ́ bí Jésù ṣe fi hàn pé àti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà.

NÍ APÁ YÌÍ

Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan

Kí nìdí tí áńgẹ́lì náà fi sọ fún ọkọ Èlísábẹ́tì pé kò ní lè sọ̀rọ̀ títí wọ́n á fi bí ọmọ náà?

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì Lọ Sọ́dọ̀ Màríà

Ó fún un ní ìròyìn tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.

Àwọn Áńgẹ́lì Kéde Pé Wọ́n Bí Jésù

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó gbọ́ ìkéde náà gbéra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Jèhófà Dáàbò Bo Jésù

Ọba búburú kan fẹ́ pa Jésù.

Nígbà Tí Jésù Wà ní Ọmọdé

Kí ló ṣe tó ya àwọn olùkọ́ inú tẹ́ńpìlì lẹ́nu?

Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀

Jòhánù sì dàgbà di wòlí ì. Ó kọ́ àwọn èèyàn pé Mèsáyà ń bọ̀. Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?