Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn. Ọmọ Ísírẹ́lì ni Nehemáyà, àmọ́ ó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọba Atasásítà ti ilẹ̀ Páṣíà. Ìlú Ṣúṣánì ló sì ń gbé. Mọ̀lẹ́bí Nehemáyà kan wá fún un ní ìròyìn burúkú nípa ipò tí ìlú Júdà wà, ó ní: ‘Àwọn tó pa dà sí Jerúsálẹ́mù wà nínú ewu. Wọn ò tíì tún ògiri àti géètì ìlú Jerúsálẹ́mù tí àwọn ará Bábílónì bà jẹ́ kọ́.’ Ohun tí Nehemáyà gbọ́ dùn ún gan-an. Ó fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí náà, ó gbàdúrà kí ọba lè fún un láyè láti lọ.

Lẹ́yìn ìyẹn, ọba ṣàkíyèsí pé inú Nehemáyà kò dùn. Ó sì bi í pé: ‘Kí ló dé tí inú rẹ kò dùn. Kí ló ṣe ẹ́?’ Nehemáyà dá a lóhùn pé: ‘Ohun tó ń bà mí nínú jẹ́ ni bí Jerúsálẹ́mù, ìlú mi, ṣe di àwókù.’ Ọba wá sọ fún un pé: ‘Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ẹ?’ Lójú ẹsẹ̀, Nehemáyà fọkàn gbàdúrà. Ó wá sọ pé: ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ tún ògiri rẹ̀ kọ́.’ Ọba Atasásítà sọ́ fún Nehemáyà pé kó lọ, ó sì rí i dájú pé òun ṣe ohun tó máa jẹ́ kí Nehemáyà dé ibi tó ń lọ láyọ̀. Ó sọ Nehemáyà di gómìnà Júdà, ó sì fún un ní igi láti fi ṣe géètì ìlú náà.

Nígbà tí Nehemáyà dé ìlú Jerúsálẹ́mù, ó yẹ ògiri náà wò. Lẹ́yìn náà, ó pé àwọn àlùfáà àti àwọn olórí jọ, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Nǹkan ti bà jẹ́ gan-an. A ní láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní kíá.’ Wọ́n gbà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ògiri ìlú náà.

Àmọ́ àwọn ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ní: ‘Tí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun ògiri tí wọ́n ń kọ́, ó máa wó o lulẹ̀.’ Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kò dá wọn lóhùn, ńṣe ni wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ. Wọ́n mọ ògiri náà, ó ga ó sì lágbára.

Àwọn ọ̀tá náà tún gba ọ̀nà míì yọ sí wọn láti gbéjà ko ìlú Jerúsálẹ́mù kí iṣẹ́ náà lè dáwọ́ dúró. Nígbà tí àwọn Júù gbọ́ nípa ohun tí wọ́n pinnu láti ṣe, ẹ̀rù bà wọ́n. Àmọ́ Nehemáyà sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Jèhófà wà pẹ̀lú wa.’ Ó wá ṣètò àwọn ẹ̀ṣọ́ láti dáàbò bo àwọn òṣìṣẹ́. Fún ìdí yìí, àwọn ọ̀tá kò lè gbéjà kò wọ́n.

 Láàárín ọjọ́ méjìléláàádọ́ta [52] péré, wọ́n parí kíkọ́ ògiri náà àti géètì rẹ̀. Nehemáyà kó àwọn ọmọ Léfì wá sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe ayẹyẹ ìparí iṣẹ́ náà. Ó pín wọn sí àwùjọ akọrin méjì. Wọ́n fi àtẹ̀gùn gun ògiri náà ní Ẹnubodè Ojúsun, àwùjọ kan gba apá ọ̀tún, àwùjọ kejì sì gba apá òsì. Wọ́n wá ń lo ohun èlò ìkọrin lóríṣiríṣi láti kọrin ìyìn sí Jèhófà. Ẹ́sírà wà pẹ̀lú àwùjọ kan, Nehemáyà sì wà lọ́dọ̀ àwùjọ kejì. Wọ́n wá pàdé ara wọn ní tẹ́ńpìlì. Gbogbo àwọn èèyàn náà lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé lágbà ló rúbọ sí Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe àjọyọ̀. Kódà àwọn tó wà lọ́nà jíjìn ń gbọ́ ariwo bí inú wọn ṣe ń dùn.

“Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.”​—Aísáyà 54:17