Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 59

Ọ̀dọ́kùnrin Mẹ́rin Ṣègbọràn sí Jèhófà

Ọ̀dọ́kùnrin Mẹ́rin Ṣègbọràn sí Jèhófà

Nígbà tí Nebukadinésárì mú àwọn ọmọ aládé Júdà lẹ́rú lọ sí Bábílónì, ó sọ pé kí òṣìṣẹ́ ààfin kan tó ń jẹ́ Áṣípénásì máa bójú tó wọn. Nebukadinésárì wá sọ fún Áṣípénásì pé kí ó wá àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ara wọn le, tí wọ́n sì gbọ́n dáadáa lára wọn. Kí wọ́n kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹ́ta. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí á jẹ́ kí wọ́n lè dé ipò pàtàkì nínú ìjọba Bábílónì. Wọ́n kọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà ní ìwé kíkà, ìwé kíkọ àti bí wọ́n ṣe lè sọ èdè Ákádíánì ti ilẹ̀ Bábílónì. Oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní ààfin ni wọ́n retí pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà máa jẹ. Orúkọ mẹ́rin lára wọn ni Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. Àmọ́ Áṣípénásì fún wọn ní orúkọ Bábílónì, ìyẹn Bẹliteṣásárì, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Ṣé ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà máa mú kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀?

 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin yìí pinnu pé àwọn máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Wọ́n tún mọ̀ pé kò yẹ kí àwọn jẹ oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní ààfin torí pé Òfin Jèhófà sọ pé wọ́n kò gbọ́dọ̀ jẹ irú àwon oúnjẹ kan tí wọ́n ń jẹ níbẹ̀. Torí náà, wọ́n sọ fún Áṣípénásì pé: ‘Jọ̀wọ́ má ṣe fún wa ni oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ ní ààfin.’ Áṣípénásì dáhùn pé: ‘Tí ẹ kò bá jẹun, ńṣe lẹ máa rù, bí ọba bá sì rí i, ó máa pa mí!’

Dáníẹ́lì wá sọ pé kó jẹ́ kí àwọn dá ọgbọ́n kan. Ó ní: ‘Máa fún wa ní ẹ̀fọ́ àti omi fún ọjọ́ mẹ́wàá. Kí o wá wò ó bóyá àwọn tó ń jẹ oúnjẹ ọba máa dára jù wá lọ.’ Áṣípénásì gbà pẹ̀lú wọn.

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dára ju àwọn ọmọkùnrin tó kù lọ. Inú Jèhófà dùn gan-an torí pé wọ́n ṣègbọràn sí i. Ó sì fún Dáníẹ́lì ní ọgbọ́n tó lè fi lóye ìtumọ̀ àlá àti ìran.

Nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn parí, Áṣípénásì kó gbogbo àwọn ọmọkùnrin náà wá síwájú Nebukadinésárì. Nígbà tí ọba bá wọn sọ̀rọ̀, ó rí i pé Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà gbọ́n ju àwọn ọmọkùnrin yòókù lọ. Ó wá yan àwọn mẹ́rin yìí láti máa ṣiṣẹ́ ní ààfin rẹ̀. Ọba sì máa ń gba ìmọ̀ràn lórí àwọn nǹkan pàtàkì lọ́dọ̀ wọn. Kódà, Jèhófà tún mú kí wọ́n gbọ́n ju àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn pidánpidán tó wà ní ààfin ọba lọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú míì ni wọ́n wà, Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà kò gbàgbé pé èèyàn Jèhófà ni àwọn. Ṣé ìwọ náà á máa rántí Jèhófà kódà nígbà tí àwọn òbí rẹ kò bá sí pẹ̀lú rẹ?

“Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, di àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.”​—1 Tímótì 4:12