Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Ẹ̀KỌ́ 63

Ọ̀rọ̀ Tó Hàn Lára Ògiri

Ọ̀rọ̀ Tó Hàn Lára Ògiri

Nígbà tó yá, Bẹliṣásárì di ọba Bábílónì. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ó pe ẹgbẹ̀rún kan [1,000] lára àwọn èèyàn pàtàkì ìlú láti wá ṣe àríyá. Ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n kó àwọn kọ́ọ̀bù tí wọ́n fi góòlù ṣe wá, èyí tí Nebukadinésárì kó nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Bẹliṣásárì àti àwọn àlejò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn kọ́ọ̀bù náà mu ọtí, wọ́n sì ń yin òrìṣà wọn. Lójijì, wọ́n rí ọwọ́ kan tó ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọn kò mọ̀ sára ògiri.

Ẹ̀rù ba Bẹliṣásárì gan-an. Ó pe àwọn pidánpidán rẹ̀, ó sì ṣèlérí fún wọn pé: ‘Ẹni tó bá lè ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún mi, mo máa sọ ọ́ di igbá kẹta mi.’ Gbogbo wọn gbìyànjú, àmọ́ kò sí ẹni tó lè ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn. Ayaba wá sọ pé: ‘Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Dáníẹ́lì, òun ló máa ń ṣàlàyé nǹkan fún Nebukadinésárì. Ó lè sọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí fún yín.’

Nígbà tí Dáníẹ́lì dé ọ̀dọ̀ ọba, Bẹliṣásárì sọ fún un pé: ‘Tí o bá lè ka ọ̀rọ̀ yìí tí o sì ṣàlàyé rẹ̀, màá fún ẹ ní ìlẹ̀kẹ̀ góòlù kan, màá sì sọ ẹ́ di igbá kẹta mi.’ Dáníẹ́lì sọ pé: ‘Mi ò fẹ́ ẹ̀bùn rẹ, àmọ́ mo máa sọ ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí. Nebukadinésárì tó jẹ́ bàbá rẹ jẹ́ agbéraga, Jèhófà sì rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀. Ìwọ náà mọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà yẹn, síbẹ̀ o rí Jèhófà fín, torí pé ò ń fi kọ́ọ̀bù tí wọ́n kó látinú tẹ́ńpìlì Rẹ̀ mu wáìnì. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run kọ rè é: Ménè, Ménè, Tékélì àti Párásínì. Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí pé àwọn ará Mídíà àti Páṣíà máa ṣẹ́gun Bábílónì, o kò sì ní jẹ́ ọba mọ́.’

Ògiri ìlú Bábílónì lágbára gan-an, omi ńlá ló sì yí ìlú náà ká. Ńṣe ló dà bíi pé kò sí ẹni tó lè ṣẹ́gun wọn. Ṣùgbọ́n alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ni àwọn ará Mídíà àti Páṣíà gbógun jà wọ́n. Kírúsì ọba Páṣíà ní kí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbẹ́ ọ̀nà tí omi náà á gbà ṣàn lọ, kí wọ́n lè rọ́nà wọnú  ìlú náà. Nígbà tí wọ́n dé ẹnu ọ̀nà, gbayawu ni ilẹ̀kùn wà! Làwọn ọmọ ogun bá ya wọlé, wọ́n ṣẹ́gun Bábílónì, wọ́n sì pa Bẹliṣásárì. Kírúsì wá di ọba Bábílónì.

Láàárín ọdún yẹn, Kírúsì kéde pé: ‘Jèhófà ti sọ fún mi pé kí n lọ tún tẹ́ńpìlì rẹ̀ tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti ṣèrànwọ́ lè lọ ṣe bẹ́ẹ̀.’ Torí náà, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Jèhófà ṣe, ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù ló pa dà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún tó ti pa run. Kírúsì dá gbogbo kọ́ọ̀bù góòlù àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí Nebukadinésárì kó nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà pa dà. Ṣé o rí bí Jèhófà ṣe lo Kírúsì láti ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́?

“Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú, ó sì ti di ibi gbígbé àwọn ẹ̀mí èṣù.” ​—Ìṣípayá 18:2